Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún: N kò bá tí ba ẹnu jẹ́ lọ́jọ́ ìgbeyàwó, àwàdà ni mo se

Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún: N kò bá tí ba ẹnu jẹ́ lọ́jọ́ ìgbeyàwó, àwàdà ni mo se

Ọkọ iyawo kan to bu sẹkun lọjọ ayẹyẹ igbeyawo rẹ, ti BBC Yoruba mu iroyin rẹ wa fun yin, Ọladapọ Ifẹoluwa ti salaye pe, oun mọọmọ fi adun sinu ayẹyẹ igbeyawo oun ni lati da awọn eeyan lara ya.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọladapọ ni oun ko fẹ ki ayẹyẹ naa tete su awọn eeyan ni oun se da ara to to bẹẹ.

O fi kun pe, aworan bi oun se ba ẹnu jẹ lọjọ igbeyawo, ti BBC Yoruba lo lori Facebook rẹ, ti ọpọ eeyan si n sọ ero ọkan wọn lori rẹ, ni oun ko mọ pe yoo rin jinna to bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkọ iyawo ẹlẹkun, ẹni to ka ọpọ ohun tawọn araalu sọ nipa aworan naa sita, wa tako ero ọpọ eeyan nipa rẹ.

Ọladapọ ni, ojisẹ Ọlọrun ni oun, bẹẹ ni oun ko mu ẹmu ri debi eroja Codeine, kii si se orogun iya oun lo duro bii iya oun lọjọ igbeyawo naa.