Nigeria 2019 Elections: Kíni o mọ̀ nípa Jimi Agbaje tó ń díje fún gómìnà ìpínlẹ̀ Eko

Jimi Agabje
Àkọlé àwòrán Kini o mọ nipa Jimi Agbaje to n dije fun Gomina ipinle Eko

Olujimi Joseph Kolawole Agbaje ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí jẹ ní a bí ní ọjọ́ kejì, oṣù kẹta ọdún 1957 sí ìdílé olóyè Julius Kosebinu tó jẹ òsíṣẹ́ ilé ìfowópamọ àti abilekọ Magret Olabisi to jẹ́ olùkọ́, àbíkejì nínú ọmọ márùn ni ọmọ bàbá rẹ̀ sì ni Segun Agbajé tó jẹ́ aláṣẹ àti olùdárí ilé ìfowópamọ́ GTbank.

Ilé ẹkọ́ ti Jimi Agbaje ti lọ

Ó lọ sí ilé-ìwé St Mary's Private School, ilú Eko àti Corona School ní Apapa fún ilé ẹkọ́ alákọbẹ̀rẹ̀, Gregory's College ní ìpínlẹ̀ Eko fún ilé ẹkọ girama, ó tún lọ sí ilé-ìwé fásìtì ilé Ifẹ tó ti di Awololwo University Ile-Ifẹ níbi tó ti kọ ẹkọ́ ìmọ̀ ìpoogùn (Pharmacist).

Yatọ sí pé Jimi Agbaje jẹ́ ìlúmọọká olóṣèlú síbẹ̀ ó ti fi àmì hàn nínú ìṣẹ́ tó yàn láàyò gẹ́gẹ́ bii apòògùn ó ṣì tún jẹ́ olùdássílẹ̀ JayKay Pharmaceutical àti Chemical ti ó sì jk olùdari titi di ọdún 2005 nígbà ti ó rárí wọn agbo òṣèlú. Oun ní olùdarí Vigeo Holding, akọweé gbogbogbò fún ẹgbẹ́ apòògùn lórílẹ̀-èdè Naijíríà 1989-1993, alága ẹgbẹ olóògùn Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Eko 1994-1997.

Image copyright Jimi Agbaje@official
Àkọlé àwòrán Kini o mọ nipa Jimi Agbaje to n dije fun Gomina ipinle Eko

Jimi Agbaje lágbo òṣèlú

Olujimim Agbaje bẹ̀rẹ̀ Oselú pẹ́lú jíjàjàgbara nígbà ìdìbò Mohood Abiola ti wọn yí dànù pẹ̀lú àwọn Pat Utomi, Asue Ighodalo, Oby Ezekwesili sì ṣe ṣẹ́ ìjagbara Lẹ̀yìn tó bẹ̀rẹ̀ òṣèlú lọ́dún 2007 ní ó kọ̀kọ́ wọ ẹgbẹ́ òṣèlú Action Congress, lẹ̀yìn náà ló lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú Democratic Peolple Alliance(DPA), nínú ẹgbẹ́ yìí ní Agbaje tí kọ́kọ́ gbégbá ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Eko èyí tó pada jámọ Babatunde Fashola lọ́wọ́.

Ó wà lára àwọn olùdíje gomínà mọ́kànlá tó pẹ̀yìda kúrò nínú ẹgbẹ́ òsèlú Action Congress lọdún 2007, lásìkò tí wọn fẹ̀sùn kan pé gómìnà tẹ́lẹ̀rí Bola Tinubu tí ni ẹni ami òróró tó yàn láti gbajọba lẹ́yìn rẹ̀ kí wọn to ṣe ìdìbò abẹ́lé

Image copyright Jomo@official
Àkọlé àwòrán Kini o mọ nipa Jimi Agbaje to n dije fun Gomina ipinle Eko

Ó kúrò nínú ẹgbẹ́ DPA lọ́dún 2011 láti darapọ̀ mọ Peoples Democratic Party (PDP) lẹ́yìn ti INEC yọ orukọ ẹgbẹ́ náà kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣelú.

Ní ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2014 ó jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bíi olúdije gómínà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ oṣèlú PDP fún ọdún 2015 lẹ́yín to fẹ́yìn Musiliu Obanikoro jánlẹ̀ níbi idibo kòmẹsẹyọ.

Image copyright Jimi@offical
Àkọlé àwòrán Kini o mọ nipa Jimi Agbaje to n dije fun Gomina ipinle Eko

Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ alábojuto lórí gbàrọgudù òògùn oyìnbo (1989-1993)

Olùdarí ilé iṣẹ́ apòògùn Jaykay Pharmaceutical & Society Ltd

Olúdari Viego Holdings Ltd

Bakán náà Olujimi Agbaje tí gba ami ẹyẹ nínú ẹgbẹ́ Pharmaceutical Society of Nigeria.

Ó fẹ́ ìyàwó Abiola Agbaje ( nee Bankole), agéjórò ni. Ọlọ́rún fíọmọ mẹ́ta tawọn lọ́rẹ