Nass: A ó tí ilé aṣòfin pa fún ọjọ́ méjì

Àkọlé àwòrán Awọn oṣìṣẹ́ fẹ̀hónú hàn níle ìgbìmọ̀ Aṣofin

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìgbìmọ́ Aṣòfin l'Abuja tí bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ̀hónú hàn nínú ọgba ilé iṣẹ́ náà lórí àìsan owó oṣù.

Òṣìṣẹ́ lábẹ́ àsìá Paliamentary Staff Association of Nigeria (PASAN) lógún lọ́gọ̀ wọn ti pé jọ̀ sí ààrín yàrá ìgbàlejo ilé ìgbìmọ̀ àsofin, wọn lérí pé awọn yóò ti ilé asofin pa tí wọn ò bá san owó osù àti àwọn ajẹmọnu mìíràn to yẹ ki wọn san.

Àkọlé àwòrán Awọn oṣìṣẹ́ fẹ̀hónú hàn níle ìgbìmọ̀ Aṣofin

Nínú àtẹ̀jáde ti akọwé PASAN fọ́wọ́ sí Comrade Suleiman Haruna, ní àwọn òṣìṣẹ́ náà tí sàlayé pé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ní pé àwọn yóò wọ́de ìfẹ̀hónú hàn láti dí ìgbòkègbòdò ilé ìgbìmọ̀ àsṣòfin lọ́wọ́ lónìí tíí ṣe ọjọ́ kerin àti ọjọ́ kẹjọ oṣù yìí, ọdún 2018.

Harun sàlàyé pé ìgbéṣẹ̀ yìí pọn dandan nítori pé àwọn fẹ́ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn kìí ṣe àwadà rárá bí kò ṣe pé ki àwọn aláṣẹ́ sàn àwọn owó oṣù àti àwọn owó ìgbéga ti wọn jẹ òṣìṣẹ́ ní wàrà-ń-sesà.

Àkọlé àwòrán Awọn oṣìṣẹ́ fẹ̀hónú hàn níle ìgbìmọ̀ Aṣofin

Ọkan lára àwọn oṣìṣẹ́ ọ̀hún sọ pé ìwọ́dé náà yóò máà wáyé láàrin aago mẹ́jọ ààrọ sí aago méjì ọsàn àwọn ọjọ́ tí àwọn fi léde.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ olùdarí ọ̀rọ̀ tó ń lọ àti ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Rawlings Agada sàlàyé pé sísàn àwọn owó àjẹmọnu kàn kọ́já àgbàra àwọn aláṣẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin, ó fi kún-un pé sísàn CONLESS ti ju agbára àwọn ìgbìmọ alákoso lọ nítorí kò sí nínú ètò ìṣúná owó fún ọdún 2018.