Cardi B ti pín yà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ Offset lẹ́yìn ọdún kan

Rappers, Offset and Cardi B Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Cardi B àti Offset ṣeré pọ̀ lọ́jọ́ Àìkú tó jẹ́ ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kọọ̀kànlá.

Akọrin takasufe Amerika Cardi B ti kede ipinya pẹlu ọkọ rẹ, Offset, ọdun kan lẹyin igba ti wọn ṣe igbeyawo.

Obirin naa to jẹ iya ọmọ kan sọ pe yoo pẹ diẹ ki wọn to pin ya pata-pata nitori pe wọn jọ bimọ pọ.

Lọjọru ni Cardi B sọ eleyi di mimọ lori Instagram to si sọ wi pe oun yoo maa nifẹ olorin Migos oun lailai.

Awọn akọrin mejeeji naa jọ kọrin pọ lọjọ Aiku ni ode kan.

Ọrọ naa ka awọn eeyan lara lagbaye titi ti orukọ awọn mejeji naa si jẹ eyi ti awọn eeyan n sọ niparẹ ju lori ero ayelujara.

Related Topics

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí