Fayoṣe gba ibi ìjàmbá ọkọ̀ dé ìpolongo ìbò Atiku

Ayọdele Fayoṣe Image copyright Getty Images

Lọjọru ni iroyin kàn pé gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ní ijamba ọkọ loju ọna marosẹ afara Third Mainland ni ipinlẹ Eko.

Ninu ikede kan ti oluranlọwọ pataki fun un lori eto iroyin, Lere Ọlayinka ni ọrọ naa ti fojuhan. Botilẹ jẹ wi pe ile iwosan lo gba Fayoṣe lalejo lẹyin ijamba naa, eyi ko di i lọwọ lati ma kopa nibi eto ipolongo ibo oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ́ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar, to waye ni ilu Ibadan, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Orí yọ Fayose nínú ìjàmbá ọkọ̀

Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ leè gbéná wojú ara wọn láìpẹ́

Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ lo 'Google' láàgbáyé-Ọ̀ọ̀ni Ìlẹ̀ ifẹ̀

Amọ ṣe ẹnu ki i sin lara Fayoṣe, niṣe ni awọn eniyan ti n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu u fun ọrọ kan to sọ pe aṣeyọri meji ti iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari labẹ ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC, ko ju pe Naijiria ti di olu ileeṣẹ fun òṣì l'agbaye, ati orilẹede kẹta ti igbesunmọmi ti wọpọ julọ lagbaye.

Ọrọ to sọ yi si tun mu ki ọpọ eniyan sọ oko eebu si ẹgbẹ́ oṣelu PDP, pe ibi ti wọn ba orilẹede Naijiria de naa lo wa bayii.

Ati wi pe Fayoṣe fun ra rẹ ṣe akoba nla fun ipinlẹ Ekiti to dari, to si fi awọn olugbe inu ipinlẹ naa sinu ebi, ìṣẹ́ ati òṣì, nitori iwa ijẹkujẹ rẹ.