Shiite: Ẹgbẹ́ Shiite fẹ́ wọ́de ní ìrántì àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn ti iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà pa

Awọn ọmọ ijọ Shiite n wde Image copyright @imnig_org
Àkọlé àwòrán Shiite tún fẹ́ fi ẹ̀hónú hàn lórí 'ọ̀pọ̀' ọmọ ẹgbẹ́ wọn ti iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà pa.

Ọkan pataki ninu ẹgbẹ ẹlẹ́sìn Shiite, Abdullahi Mohammed Musa sọ pe wọn ti kọwe pe awọn ajafẹtọ ọmọniyan, to fi mọ awọn kristẹni ati pasitọ, lati darapọ mọ iwọde ti ẹgbẹ naa fẹ ẹ ṣe.

Igbesẹ eyi ni Abdullahi sọ pe oun ni igbagbọ pe yoo yọri, nitori pe awọn pasitọ gan an n ṣe awuyewuye pe eto aabo ko fararọ ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lọjọ Ẹti ni awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin Islam Movement of Nigeria, ti awọn eniyan tun mọ si awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite, tun fẹ ẹ ṣe iwọde ifẹhonu han miran niluu Abuja, nitori ẹsun ti wọn fi kan an pe awọn ọmọ ogun pa awọn ọmọ ẹgbẹ naa l'oṣu Kẹwa, ọdun 2018.

Akọwe ẹka ikẹkọọ ninu ẹgbẹ naa, Abdullahi Mohammed Musa, sọ fun akọroyin BBC, Onyinye Chime, pe ara ohun ti yoo waye nibi ifẹhonuhan naa ni gbigbe aworan awọn ọmọ ẹgbẹ ti awọn ọmọ ogun Naijiria pa, kaakiri gẹgẹ bi ẹri, nitori ileeṣẹ ogun sọ pe mẹta pere l'awọn pa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Shiite n sọ pe o pe ogoji ọjọ bayii ti awọn ọmọ ileeṣẹ ológun Naijiria ṣekupa àwọn ọmọ ẹgbẹ àwọn to le ni aadọta lasiko ti n fi ẹhonu han lọjọ kẹtadinlọgbọn, to fi mọ ọjọ kọkandinlọgbọn si ọgbọnjọ, oṣu Kẹwa, lori olórí wọn, Ibrahim El Zakzaky ti ijọba fi sahamọ lati ọdun 2015.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPapalolo ní ìlépa owó ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn òṣèré tíátà àtijọ́ àti ìsisìnyí

Igba akọkọ kọ niyii ti awọn ọmọ gbẹ́ naa yoo fẹhonuhan lori bi ijba apapọ ṣe fi olori wn si ahamọ lati ọdun 2015, lẹyin ti ija waye laarin wọn ati awọn ọmọ ologun Naijiria.

Ifẹhonuhan to waye l'oṣu Kẹwaa, ti awọn ọmọ ologun si pa lara wọn.

ICC pari iwadi lori pipa Shiites, IPOB

Ọ̀pọ̀ èèyàn farapa nínú ìwọ́de Shiite

Gbogbo igbesẹ lati ba agbẹnusọ ileesẹ ologun, Ọgagun Kukasheka Usman, sọrọ ni ko so eso rere. O kọ lati gbe ìpè rẹ lẹyin ti oun ati akọroyin BBC kọkọ fi atẹjisẹ ba ara wọn sọrọ lori oun ti o fẹ ba a sọ.