Aisha Buhari: Àwọn alágbára ti já ìjọba gbà mọ́ ọkọ mi lọ́wọ́

Aisha Buhari Image copyright @aishambuhari
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari ní ìfẹ́ ìdájọ́ òdodo ti òun ní ló fàá tí òun fi n sọ̀rọ̀ tako ọkọ òun

Aya Aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari, ti gbaju-gbaja ni ọpọ igba, paapa fun sisọ ọrọ to tako ọkọ rẹ, Muhammadu Buhari, iṣakoso rẹ, ati ẹgbẹ oṣelu to gbe e wọle, All Progressives Congress, APC.

Eyi si ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria maa beere nipa iru ibaṣepọ to wa laarin tọkọ-taya ọhun, tabi iru ọkọ ti Aarẹ Buhari jẹ ninu ile.

Ẹ jẹ ka bojuwo awọn iye igba ti Aisha ti sọrọ nipa ijọba ọkọ rẹ ni sisẹ n tẹle:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌfipálówó: Bàbá ọmọ tí wọn gé lórí ní òun rán an láti l gbowó lẹ́nu ATM ni
  • Awọn alagbara ti ja ijọba gba mọ ọkọ mi lọwọ

Igba akọkọ ti Aisha Buhari kọkọ sọrọ to tako iṣakoso ọkọ rẹ, o sọ pe awọn alagbara ti gba iṣakoso mọ ọkọ oun lọwọ.

O sọrọ naa lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC loṣu Kẹwa, 2016.

O ni pe "Aarẹ Buhari ko mọ eniyan marundinlogoji ninu aadọta to yan sipo nigba naa, ati pe emi paapa ti mo ti jẹ iyawo rẹ fun ọdun mẹtadinlọgbọn ko mọ wọn."

Image copyright @aishambuhari

Awọn kan joko sinu ile wọn jẹjẹ ni lasiko ta n se wahala eto idibo, ṣugbọn niṣe ni wọn ransẹ pe wọn lati wa jẹ olori ileeṣẹ ijọba tabi di minisita."

Ṣaaju ki Aisha to sọrọ ni ita gbangba, ni ọpọlọpọ eniyan ti n fi ẹsun kan Aarẹ Muhammadu Buhari pe, ọwọ awọn ìbátan rẹ kan, bi i Mamman Daura, ni iṣakoso orilẹede Naijiria wà.

Ọrọ ti Aisha sọ yii ya ọpọlọpọ eniyan lẹnu pe, o le sọ iru nkan bẹ ẹ tabi bu ẹnu ẹtẹ lu iṣakoso ọkọ rẹ ni gbangba.

Buhari ni ifesi si ọrọ yii, lasiko to wa ni orilẹede Germany nigba ti iyawo rẹ sọrọ naa, sọ pe "mi o mọ ẹgbẹ oṣelu ti iyawo mi n ṣe, ṣugbọn ibujoko rẹ n bẹ nile idana mi, to fi mọ iyara igbalejo mi, ati inu yara miran.''

  • Mi o ni ṣatilẹyin fun ọkọ mi to ba fẹ lọ fun saa keji

Igba keji ti Aisha Buhari tun sọrọ lodi si iṣakoso ọkọ rẹ ni ọdun 2017 nigba to sọ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun ọkọ oun to ba dije fun saa keji gẹgẹ bi aarẹ l'ọdun 2019.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Aisha sọ pe oun bi oun ṣe n 'fọ aṣọ idọti ọkọ oun ni gbangba' kii ṣe nitori afojudi, ṣugbọn nitori o jẹ otitọ ti oun gbọdọ sọ.

Image copyright @aishambuhari

Bakan naa lo fi kun un pe ihuwasi oun ko ṣẹyin bi oun ṣe ri wi pe awọn awọn to sun mọ ọkọ oun n lo agbara ti ara ilu gbe e wọ ni ilokulo.

Aisha sọ pe 'ti ọkọ mi ko ba wa atunṣe si awọn kudiẹ-kudiẹ to wa ninu iṣakoso rẹ titi di ọdun 2019, mi o ni jade lọ ba a polongo ibo tabi kesi obinrin kankan lati dibo fun un.

  • O polongo fidio awọn sẹnetọ kan to tako ọkọ rẹ̀

Igba miran tun ni asiko to fi awọn fidio kan sita. Awọn fidio naa safihan awọn sẹnetọ meji kan ti ko gba t'ọkọ rẹ sita loju opo Twitter rẹ.

Awọn sẹnetọ meji naa ni Isah Misau ati Ben Murray-Bruce.

Ninu ọkan ninu awọn fidio naa, Sẹnetọ Misau sọ pe oun ko faramọ bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe yan ẹni ti m'ọṣẹ si ipo Oludari Agba fun ajọ Ọtẹlẹmuyẹ Naijiria.

Ekeji ti Aisha tun fisita ṣafihanbi Sẹnetọ Ben Bruce ṣe n sọ pe orilẹede Naijiria jẹ ilu ti ko ni ofin ati ilana.

Awọn fidio naa ti Aisha Buhari fi sita fa awuyewuye lori ẹrọ ayelujara, ti ọpọ eniyan si bẹrẹ si ni foju wo o gẹgẹ bi alatako gboogi fun Aarẹ.

  • Ẹgbẹ́ APC n fi ẹtọ awọn ọmọ ẹgbẹ́ dun wọn

Igba miran ti Aisah Buhari tun mi ori ẹrọ ayelujara ni asiko ti o sọrọ tako eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC labẹ iṣakoso Adams Oshiomole.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Aisha sọ pe eto idibo naa kun fun fifi ẹtọ ẹni dun ni, pẹlu alaye pe ẹgbẹ yọ orukọ awọn oludije kan to ti ra fọọmu lati dije kuro l'ọjọ idibo.

O sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC to n polongo ayipada yẹ ko le fi apẹrẹ rere han.

Sugbọn awọn kan sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ara lo n ta Aisha Buhari, nitori pe aburo rẹ kan, Halilu Mahmud kuna ninu idibo abẹle sipo gomina nipinlẹ Adamawa.

  • Awọn ọkunrin meji kan lo n dari ijọba ọkọ mi

Laipẹ yii ni fidio kan tun jade to ṣafihan Aisha Buhari to sọ pe awọn ọkunrin alagbara meji kan lo n dari iṣakoso ọkọ oun.

Aisha sọrọ naa nibi ipade apero kan to waye nilu Abuja pe awọn mejeeji ọhun, to kọ̀ lati darukọ, lo jẹ idiwọ ati idena fun idagbasoke orilẹede Naijiria.

Image copyright @aishambuhari
Àkọlé àwòrán Aisha Buhari ní ìfẹ́ ìdájọ́ òdodo ti òun ní ló fàá tí òun fi ṣe bẹ́

Aisha ṣalaye ninu fidio naa pe ''aṣeyọri iṣakoso ọkọ oun ko ba pọ ju boṣe wa lọ, ṣugbọn awọn alagbara mejeeji yii ni igi wọ́rọ́kọ́ to n da ina a ru.''

Ọrọ to sọ yi n fa ariyanjiyan, pẹlu bi awọn kan ṣe n sọ pe o ṣeeṣe ki aarẹ Muhammadu Buhari ma a koju igbelewọn ninu ile gẹgẹ bi ọkọ, bi ko ṣe koju oṣuwọn gẹgẹ bi aarẹ.

Bakan naa ni awọn kan n sọ pe, kii ṣe gbogbo aṣọ lo yẹ ka maa ṣa l'oorun nipa iṣakoso ọkọ gẹgẹ bi aya arẹ.