Ooni Ile Ife: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀ọ̀ni Ilẹ̀ ifẹ̀ to pe Ọdún mẹ́ta lórí ìtẹ́ Òdùduwà

Ọọni ifẹ Image copyright Ooni ile ife
Àkọlé àwòrán gomina ipin#sun nigba naa, Rauf Arẹgbẹṣọla gbe ọpa aṣẹ funi tuntun nibi ayẹyẹ nla to waye ni gbagede Ẹnuwa ni aafin Oodua ni ilu ile Ifẹ

Ṣaaju ọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2015, ko si ẹni to leero pe Adeyẹye Ogunwusi lee gun ori itẹ Oodua gẹgẹ bii Ọọni ile ifẹ nitori bi ọba kan ko ba ku, omiran kii jẹ.

Ọjọ yii gan an ni Ọọni ana, Okunade Ṣijuwade Olubuṣe keji waja ti igbesẹ ati yan Ọọni tuntun bẹrẹ.

Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwa ọdun 2015 ni awọn afọbajẹ ni Ilẹ Ifẹ kede orukọ Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi gẹgẹ bii Ọmọ oye ti yoo jẹ Ọọni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ti eto gbogbo to, ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2015 ni gomina ipinlẹ Ọṣun nigba naa, Rauf Arẹgbẹṣọla gbe ọpa aṣẹ fun un nibi ayẹyẹ nla to waye ni gbagede Ẹnuwa ni aafin Oodua ni ilu ile Ifẹ.

Lati igba yii wa ni Ọọni Ogunwusi ti bẹrẹ iṣẹ ti gbogbo ọmọ Yoruba ni ilẹ yii ati oke okun si ti n kan saara si.

Image copyright Ooni ile ife
Àkọlé àwòrán Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 2015 ni wọ́n kéde orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ oyè tí ifá mú

Ohun mẹta ni o farahan ninu awọn ohun ti Ọọni Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II gbajumọ julọ ni

i.Idagbasoke awọn ọdọ

ii.Igbesoke alaafia laaarin awọn lọbalọba ati gbogbo Yoruba lapapọ

iii.Ironilagbara ati idagbasoke ọmọniyan.

Kaakiri agbaye si ni Ọọni ti lọ lati lọ igi ifẹ, iṣọkan ati idagbasoke Yoruba ati gbogbo ọmọniyan ni alọye.

Image copyright Ooni ife
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ kéje oṣù kéjìlá ọdún 2015 ni Adeyeye Enitan Ogunwusi gba ọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi Ọ̀ọ̀ni Ilẹ̀ Ifẹ̀

Awọn orilẹede bii Amẹrika, Gẹẹsi, Brazil, Cuba , Ghana ati bẹẹbẹẹ lọ ni Ọọni Ogunwusi ti de lati kan si awọn ọmọ Yoruba ti wọn gbilẹ kaakiri agbaye.

Adeyẹye ni Ọọni kọkanlelaadọta ti yoo jẹ; bẹẹni onimọ nipa iṣiro owo ti o dantọ si ni.

Ki o to de ori itẹ, o jẹ gbajugbaja oludaṣẹsilẹ ti itan tilẹ fi idi rẹ mulẹ pe ati ilu ẹkọ ni o ti bẹrẹ si ra ọwọ le okoowo ati idaṣẹsilẹ.

Image copyright Ooni ife
Àkọlé àwòrán Adeyẹye ni Ọọni kọkanlelaadọta ti yoo jẹ

Ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwa, ọdun 1974 ni wọn bi Ọọni Ogunwusi ni idile Ọba Giesi ni ile ifẹ. Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ni baba rẹ, Olurọpo.

Gẹgẹ bi itan ṣe sọ, asọtẹlẹ ti wa nipa ibi rẹ ni wọn fi sọọ ni Ẹnitan, baba baba rẹ ni o si sọọ ni Adeyẹye.

Ileewe alakọbẹrẹ Subuola Memorial Nursery and Primary School ati ileewe girama Loyola College ni ilu Ibadan ni o lọ ki o to lọ gba oye ijinlẹ HND ninu imọ iṣiro owo nile ẹkọ gbogbounṣe, the Polytechnic, Ibadan.

Image copyright Ooni ogunwusi
Àkọlé àwòrán Orukọ oye ọjaja keji ni Ọọni nlo

Ọọni Derinọla Ọlọgbẹnla ni Ọọni to jẹ kẹyin ni idile Ọba Giesi ni aarin ọdun 1880 si 1894.

Ọọni wa lara awọn ọba ti aarẹ orilẹede Naijiria ko fi ọrọ rẹ ṣawada rara.

Ko si si ẹni ri ariwisi si iwa ati iṣesi rẹ lawujọ lati igba ti o ti gun ori oye.