Ijora-Wharf bridge: Ìjọba àpapọ̀ ṣí afárá Ijora-Wharf lẹ́yìn àtúnṣe

Afara ọkọ ni ilu Eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìjọba àpapọ̀ ti afárá náà ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn fún àtúnṣe lórí àwọn kọnkéré orí afárá ọ̀hún

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti o ti wa ni titi pa, Ijọba apapọ ti ṣi afara ọkọ Ijora-Wharf ni apapọ fun lilọ bibọ ọkọ.

Ijọba ti afara naa pa fun atunṣe lati fi awọn kọnkere miran rọpọ awọn ti o ti dibajẹ lori afara naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti wọn ti afara naa pa fun atunṣe, minisita funina ọba, iṣẹ ode ati ipese ile lorilẹede Naijiria, babatunde Faṣola ni igbesẹ to le pupọ lati gbe ni igbesẹ naa, ṣugbọn ko ṣee ma gbe ni nitori ati daabo bo ọpọ ẹmi.

Minisita Faṣọla ni ko tii si atunṣe kan ti o waye lori afara naa lati ogoji ọdun sẹyin ti wọn ti kọọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionǸjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?

Pẹlu ṣiṣi afara naa, adinku yoo ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti o rin ni ilu Eko.

Bakan naa lo ṣalaye pe pupọ awọn afara kaakiri orilẹede Naijiria naa ni wọn ṣi nile irufẹ amojuto bayii nitori ailakasi awọn ijọba ti o ti jẹ kọja lorilẹede Naijiria.