Electoral bill 2018: Ní ìgbà wo gan an ni àbádòfin ìdìbò tuntun yóò di òfin?

Buhar, saraki ati dogara n ki ara wọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fún ìgbà kẹta, Ààrẹ Buhari tún ti dá àbádòfin ìdìbò tuntun padà f'áwọn aṣòfin àpapọ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari ti da abadofin ilana idibo 2018 pada fawọn aṣofin apapọ pẹlu idi pe idibo apapọ ti wọle de, bibuwọlu abadofin naa si lee da nnkan ru

Igba kẹta niyi ti aarẹ yoo maa da abadofin yii pada nitori idi kan tabi omiran.

Aarẹ Buhari fi iwe naa ranṣẹ pada sawọn aṣofin pẹlu lẹta kan eyi to kọ siwọn, ninu rẹ ni o si ti mẹnu ba, bi abadofin naa ṣe lee da edeaiyede silẹ lori ilana fun titẹle lori idibo apapọ ti yoo waye lọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ ni ki awọn aṣofin wulẹ sinmi naa di igba ti eto idibo apapọ ba pari ati pe abadofin ilana idibo tuntun naa ki wọn jẹ ki o jẹ eyi ti yoo bẹrẹ iṣẹ lẹyin idibo apapọ ọdun 2019.

Buhari tun tọka si awọn-abala mẹrin miran ninu abadofin naa ti o fẹ ki awọn aṣofin apapọ o tun ṣe.

Amọṣa, awọn eekan ilu ati ẹgbẹ alatako gbogbo ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ arẹ yii eleyi ti awọn kan ni o ku diẹ fun idagbasoke eto iṣejọba awarawa lorilẹede Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kikuna Buhari lati buwọlu abadofin ilana eto idibo naa ti n da awuyewuye silẹ lagbo oṣelu ni Naijiria

Ajọ Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu lorilẹede Naijiria, CNPP ni aibuwọlu abadofin naa ṣaaju eto idibo apaps ọdun 2019 yoo ni ipa.

Akọwe agba fun ajs naa, Willy Ezugwu ni 'awọn alagbara kan ti wọn ko fẹran iṣejọba tiwantiwa ni wọn fẹ fi tipa tikuuku bu omi pa ina bibuwọlu abadofin ilana eto idibo naa.'

Bakan naa, ọkan pataki lara awọn sẹnetọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ ki o to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miran, Sẹnetọ Sani Shehu ni 'awọn alatako ijọba awarawa lawọn ti o n tako abadofin naa"

"Bawo ni awọn ti a gbe agbara fun ṣe lee pẹyinda lati ta kẹkẹ to gbe wọn de ipo ni ipa?"

Ninu atẹjade kan ti alukoro rẹ fi sita, ẹgbẹ oṣelu PDP ni "ẹru abajade idibo 2019 to n ba aarẹ Buhari ni ko jẹ ki o fẹ buwọlu abadofin yii nitori yoo wa ọwọ igbimọ ati ṣe eru ibo wọlẹ."

Ṣugbọn pẹlu bi ọrs ti ṣe ri yii, awọn onimọ ti n pe fun awọn aṣofin apapọ lati lo agbara aṣẹ waa ti ofin orilẹede yii fun wọn lati fi gbọwọle abadofin naa.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP gan ti fọwọ si igbesẹ bẹẹ.

Aṣofin Malachi Ugumadu ti o jẹ alaga ajọ ti o n ja fun ẹtọ araalu, CDHR lorilẹede Naijiria ṣalaye pe irufẹ iṣẹlẹ bayii ti waye ri ni ọdun 2006 ṣugbọn ti awọn aṣofin apapọ lo agbara aṣẹ waa lati buwọlu iwe abadofin naa funra wọn.

Amofin Malachi Ugumadu ni bi aarẹ ba kuna lati ṣe ohun ti o tọ, ki awọn asofin tẹ siwaju lati fi aṣẹ waa wọn gbe ofin naa wọle.