2015 Elections: Àwòrán mánigbàgbé rèé tó sọ bí ìbò 2015 ṣe lọ

Ọ̀pọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ àríkọ́gbọ́n lo wáyé lásìkò ìbò 2015 nínú èyí tí ẹgbẹ́ alátakò ti gba ìjọba lọ́wọ́ ẹgbẹ́ tó darí Nàíjíríà fọ́dún mẹ́rìndínlógún.

Muhammadu Buhari, aya rẹ, Aisha, aya igbakeji aarẹ, Dọlapọ ati Yẹmi Ọsinbajo,igbakeji aarẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin awọn ọkunrin to ba se aseyọri, awọn obinrin kan wa nibẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ibo 2015 se pataki lara awọn ọmọ Naijiria, tawọn akanda ẹda gan ko si gbale joko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aaro mẹta ti kii da ọbẹ nu nipinl ogun lasiko ipolongo ibo aarẹ tẹgbẹ APC ldun 2015

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oselu ko yẹ ko mu ẹtanu lọwọ. Ere ọwọ lasan ni

Oríṣun àwòrán, @AsoRock

Àkọlé àwòrán,

Saa laa ni, ẹnikan ko nile aye. Bi igba kan ba lọ, igba miran yoo tun de

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹni ti yoo ba jẹun gbọ̀in-gbọin yoo tilẹkun gbọin-gbọin leto idibo 2015. Se lawọn agbofinro duro gbangba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oriṣa ti ako ba fi oju ọmọde mọ ko ni pẹ parun. Awọn ọdọ to jẹ agunbanirọ ko gbẹyin ninu akoso ibo 2015

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ati okeere ni oloju jinjin ti n mu ẹkun sun lajọ INEC fi ibo 2015 se, ti ohun eelo idibo si to, o tun sẹkun si agbala wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Inu ẹni kii dun, ka paa mọra. Awọn oludibo kan ko lee pa iduunu wọn mọra lẹyin ti wọn kede ibo 2015

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Àkọlé àwòrán,

Oju mẹwa ko jọ oju ẹni leto idibo 2015, tawọn eeyan ko si kọbi ara si oorun to mu yanyan, tabi jẹ ko sediwọ fun wọn lati dibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipolongo ibo lọdun 2015 lo gba awọn ọna ara yọ, abi ki ni ka ti pe gbigbe ikoko lori pẹlu awo oju ati igbalẹ lọwọ lati dibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹni ti yoo ba esu jẹun, sibi rẹ yoo gun leto idibo 2015, tawọn ologun si gba arodan si igboro lati dẹkun rogbodiyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Irawe kii dajọ ilẹ ko sun ọna. Awọn osisẹ eleto idibo tan ina soju ni alẹ lati ka ibo ni

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ba rọkọ, a ko reko, kii se ọrọ idibo 2015. Ibiti mọto ko de, wọn gbe ọkada de ibẹ lati pin ohun eelo idibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹ bami wa orukọ mi, mo gbọdọ dibo loni ni. Ero yii lo seese ko maa wa lọkan arakunrin yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oju gbogbo agbaye lo se mẹrin pẹlu idibo 2015