Ẹ wo fídíò bí Ìyálóde Ìbàdàn se sùn tẹ̀yẹ-tẹ̀yẹ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aminat Abọdun: Ọ̀pọ̀ èèyàn se ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún akọni obìnrin tó lọ

Ọjọ manigbagbe ni ọjọ Aiku nilẹ Ibadan nigba ti wọn fi tiyi-tẹyẹ ki Iyalode ilẹ Ibadan, Oloye Aminat Abiọdun pe o digbose.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Lekan Alabi ni Iyalode Abiọdun jẹ onisowo lati kekere, to si ri ja jẹ.

Lero ti Agba Amofin Adeniyi Akintọla, "General lo yẹ ka maa pe Aminat Abiọdun, ko se fi ọwọ rọ sẹyin lawujọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O mọ oge se, kii jẹ ounjẹ iwọsi, ko si si ẹni ti ko lee wo oju rẹ.

Awọn ọmọ ati ọmọ oloogbe to ba wa sọrọ ni, Iyalode to di oloogbe naa ni aajo ọmọ, o nibẹru Ọlọrun, ti ko si si isoro ti ko lee ba eeyan yanju rẹ.

Ọpọ eekan ilu nilẹ Ibadan, nipinlẹ Ọyọ ati nilẹ Yoruba lo peju sibi ẹyẹ ikẹyin ti wọn se fun Oloye Aminat Abiọdun.