Fela Durotoye: ọmọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n tó di olóṣèlú Nàìjíríà

Fela Durotoye Image copyright @feladurotoye
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2018 ni Fẹla Durotoye kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria

Ta ni Fẹla ọmọ Durotoye?

Fun ẹni ti o ba mọ itan oṣelu orilẹ-ede Naijiria fun igba diẹ sẹyin,, orukọ Fẹla Durotoye ko lee jẹyọ gẹgẹ bii ara awọn oloṣelu atigbadegba lorilẹ-ede Naijiria.

Ọjọ kejila, oṣu karun, ọdun 1971 ni wọn bi Fẹla Durotoye gẹgẹ bii Adetokunbọ Oluwafẹọlami Durotoye.

Ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ ni baba ati iya rẹ, Layiwọla ati Adeline Durotoye ni fasiti Ibadan ki wọn to lọ si fasiti ilu Ifẹ eyi ti o ti di Obafemi Awolowo University, OAU bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Fẹla Durotoye:

Ọrọ Fẹla Durotoye yatọ si ọpọ awọn oloṣelu nitori pupọ awọn oloṣelu lorilẹ-ede Naijiria lode oni, papa julọ awọn ti wọn n dupo aarẹ ni awọn tabi baba ati iya wọn ti wa lẹnu owo oṣelu fun ọpọlọpọ ọdun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 Elections: Èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lóri ètó àlùfáà tàbí ìmámù lásìkò ìbò

Ni fasiti Obafemi Awolowo yii ni Fela Durotoye ti kẹkọ gboye imọ ẹrọ Kọmputa pẹlu eto ọrọ aje ki o to tun kawe gba imọ kun imọ pẹlu ẹkọ imọ ijinlẹ keji, MBA ni fasiti OAU yii kan naa ki o to tun wa imọ lọ si gbajugbaja fasiti ni, Havard University ni orilẹ-ede Amẹrika.

Image copyright @feladurotoye
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun 2018 ni wọn yan an gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu naa

Ogunna gbongbo onimọ nipa iṣuna ni Fẹla Durotoye.

O ti ṣiṣẹ pẹlu ọpọ ileeṣẹ ja-n-kan-ja-n-kan kaakiri agbaye bii Ventures and Trust Limited, Phillips consulting limited ki o to lọ da ileeṣẹ V.I.P Consulting limited silẹ ni ọdun 2000.

Image copyright @Fela2019
Àkọlé àwòrán Ọjọ kejila, oṣu karun, ọdun 1971 ni wọn bi Fẹla Durotoye gẹgẹ bii Adetokunbọ Oluwafẹọlami Durotoye

Gbajugbaja onimọ ati olukọni nipa ọrọ akoso ati idari ni Fẹla Durotoye ti o si ti ṣe idanilẹkọ fun ọpọ ni ilẹ yii ati ni oke okun.

Ni bayii, Fẹla ni aarẹ ileeṣẹ GEMSTONE Nation Builders Foundation, ileeṣẹ ti ko gbara le ijọba ti ko si le ere ninu iṣẹ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFestus keyamo: Ọ̀rọ̀ Obasanjọ sí Buhari ti di ìrégbè

Ni oṣu kejila, ọdun 2009 ni o lewaju awọn eekan ilumọọka lagbo amuludun lorilẹ-ede Naijiria bii, Banky W, Alibaba, Kate Henshaw, Omoni Oboli, Teju Babyface, Sound Sultan, TY Bello, Dj Jimmy Jatt, Omawunmi, Denrele, Dele Momodu, Tosin Bucknor, Stella Damascus, Tee A, Segun Dangote, Ebuka Obi ati bẹẹbẹẹ lọ fun eto kan ti o pe ni "Mushin Makeover" eyi ti wọn fi tu ọpọ ile ni agbegbe Mushin nipinlẹ Eko kun fun ayika to gbayii.

Image copyright @feladurotoye
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2018 ni Fẹla Durotoye kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria

Ko din ni ẹgbẹrun meji awọn eeyan ti wọn korajọ fun eto yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

O tó bií ile mẹrindinlaadọọrun ti wọn kun. Lẹyin o rẹyin, ọgọrun un awọn ọdọ ni wọn ni ileeṣẹ apọda Berger Paints PLC kọ ni iṣẹ ile kikun lọna igbalode ti awọn pẹlu si di ẹni ti o n fi iṣẹ naa jẹun bayii.

Image copyright @feladurotoye
Àkọlé àwòrán Ni oṣu kejila, ọdun 2009 ni o lewaju awọn eekan ilumọọka lagbo amuludun fun eto kan ti o pe ni "Mushin Makeover" eyi ti wọn fi tu ọpọ ile ni agbegbe Mushin nipinlẹ Eko kun fun ayika to gbayii

Ni ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2018 ni Fẹla Durotoye kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lasiko idibo apapọ ọdun 2019 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Alliance for New Nigeria, ANN.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan an, ọdun 2018 ni wọn yan an gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu naa.

Image copyright @feladurotoye
Àkọlé àwòrán Ọjọ kejila oṣu karun ọdun 1971 ni wọn bi Fẹla Durotoye gẹgẹ bii Adetokunbọ Oluwafẹọlami Durotoye

Ṣe wọn ni eeyan bi ahun naa nii ri ahun he, gbajugbaja agbanisiṣẹ bii tirẹ, Tara Fẹla-Durotoye ni Fẹla fẹ ni iyawo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Tara jẹ amofin ati aṣaraloge. Oun si ni oludasilẹ ileeṣẹ aṣaraloge House of Tara.

Ọmọ ọkunrin mẹta ni wọn bi ti orukọ wọn a si maa jẹ Mobolurin, Demilade & Morolaoluwa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀tọ̀ ni nkan tí wọ́n sọ fún ẹbí rẹ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n fi n ṣe