Nigeria Elections 2019: Dapo Abiodun, ǹkan márùn ún tó yẹ kẹ́ẹ mọ̀ nípa rẹ̀

Dapo Abiodun Image copyright Twitter/Dapo Abiodun
Àkọlé àwòrán Ìgbìmọ̀ amúsẹ́yé ẹgbẹ́ òsèlú APC ti polongo Dapo Abiodun gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òsèlú APC ní ìpínlẹ Ogun.

Ẹgbẹ oselu APC ni ipinlẹ Ogun ti polongo Dapo Abiodun gẹgẹ bi ẹni ti yoo gbe asia oludije sipo gomina ni idibo gbogboogbo ti 2019.

Bi Dapo Abiodun ba jawe olubori ni idbo gbogboogbo ti ọdun 2019, oun ni yoo gba ijọba lọwọ gomina Ibikunle Amosun ti ipinlẹ Ogun.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, Osu Karun, ọdun 1960 ni wọn bi ọmọọba Dapo Abiodun lati ijọba ibilẹ Iperu-Remo ni ipinlẹ Ogun.

Awọn ohun marun nipa oludije sipo gomina ni ipinlẹ Ogun fun idibo ọdun 2019.

  • Dapo Abiodun kọ ẹkọ gboye onimọ ẹrọ civil engineering lati ile iwe fasiti Ọbafẹmi Awolowo ti Ile Ife, ti o si jẹ adari fun Heyden Petroleum Ltd [HPL].
  • Oludije sipo gomina naa lo bi olorintakasufe Olugbenga Abiodun aka DJ Olu to di oloogbe to si jẹ ọrẹ timọtimọ olorin takasufe Davido lorilẹede Naijria.
  • Dapọ jẹ ọkan gboogi lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ogun.
  • Lọdun 2015, Dapo Abiodun dije dupo fun sẹnatọ ni Ile Igbimọ Asofin Agba fun ila-oorun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP ṣugbọn ni bayii, o ti wa lẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi oludije ninu idibo gbogboogbo ti 2019.
  • Nigba ti Dapo wa ni ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ni ọdun 1993, o lọ fun ipo sẹnatọ labẹ ẹgbẹ oselu United Nigeria Congress Party(UNCP).
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.