Ìtàn Mánigbàgbé: Ẹfunsetan Aniwura lọ́lá, ó lówó, ó sì tún gbajúmọ̀

Ẹfunsetan Aniwura Image copyright @ibadaninsider

Eledua fi awọn obinrin takuntakun jinki ilẹ adulawọ, ti ọpọ wọn ko si se fi ọwọ rọ sẹyin rara.

Lara awọn obinrin takuntakun to gbe ounjẹ fẹgbẹ, to si tun gba awo bọ nilẹ Yoruba ni obinrin bi ọkunrin kan nilẹ Ibadan, Ẹfunsetan Aniwura, tii se Iyalode ilẹ Ibadan.

Niwọn igba to jẹ pe ọjọ ti pe, Iyalode Ẹfunsetan ti wa, to si ti pada sọdọ Eledua, oniruuru itan ni a gbọ nipa rẹ. Idi ni pe ko akọsilẹ to daju nipa igbe aye akọni obinrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIgun OPC: OPC ti sọnù, àwọn èèyàn ń sá fún wa láì fẹ́ darapọ̀ mọ́ wa

Itan igbesi aye Ẹfunsetan ko lọ gaara ga bo se yẹ, nitori oniruuru ọna lo pin si. Amọ wọn bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan.

Amọ, akọsilẹ oju opo Wikipedia ni a lo, lati se akojọpọ itan nipa igbe aye Ẹfunsetan Aniwura yii.

Itan igbe aye Ẹfunsetan Aniwura:

 • Laarin ọdun 1790 si 1800 ni Oloye Ẹfunsetan Aniwura de ilẹ aye. Ilu Abẹokuta, tii se ilẹ Ẹgba, eyi to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun lode oni, ni Ẹfunsetan fori sọlẹ si
 • Baba rẹ, Oloye Ogunrin jẹ akọni takuntakun lati agbegbe Ikija, nigba ti iya rẹ jẹ ọmọ bibi ilu Ile Ifẹ, to wa ni ipinlẹ Ọsun bayi
 • Onisowo pẹpẹpẹ ni iya Ẹfunsetan, eyi ti Aniwura jogun lọdọ iya rẹ, amugbooro eto okoowo yii naa lo si n ti Ẹfunsetan ni ọpọnpọn, lasiko to ba kọwọ rin pẹlu iya rẹ lọ sawọn ọja gbogbo
 • Itan ni Ẹfunsetan rin irinajo wa silu Ibadan lati wa se okoowo to gbooro nitori ilu to tobi nilu Ibadan lasiko naa, to si faaye gba okoowo nla
 • Ẹfunsetan ri jajẹ, o lowo lọwọ, o ni ẹru toto ẹgbẹrun meji ati ọpọ oko, to si n ko ire oko lọ sawọn ilu bii Porto Novo, Badagry ati Ikorodu
 • O tun dokowo ninu siga tita ati owo ẹru sise, bẹẹ lo tun maa n se eroja itọju ara labẹle
 • Ẹfunsetan se igbeyawo fun ọpọ igba amọ ọkan soso ni Ọba Oke fi ta lọrẹ, nigba ti itan miran ni ko tilẹ bimọ rara laye
 • A tun gbọ pe ọmọ ti Ẹfunsetan bi jade laye lọjọ to bi, sugbọn itan miran ni ori ikunlẹ ni ọmọ kansoso ti Ẹfunsetan bi ku si lasiko ti ọmọ naa n rọbilati bi ọmọ
 • Ìsẹ̀lẹ̀ yìí ni awọn eeyan kan sọ pe o sokunfa bi Ẹfunsetan se kilọ fun awọn ẹru rẹ pe ọkankan ninu wọn ko gbọdọ bimọ tabi loyun rara, iku ni ere ẹsẹ fawọn to ba bimọ
 • Ẹfunsetan la gbọ pe o jẹ iya isalẹ ijọ Anglican nilẹ Ibadan nitori ipa to n ko lati se amugbooro ẹsin igbagbọ
 • Ọdun 1860 ni wọn fi Aniwura jẹ Iyalode ilẹ Ibadan amọitan ni Aarẹ Latoosa gba oye naa lọwọ rẹ lọdun 1874
 • Ọ́pọ igba la gbọ pe aawọ maa n waye laarin Latoosa ati Ẹfunsetan, ti wọn kii si ri imi ara wọn latan, tori pe Ẹfunsetan maa n gbo lẹnu
 • Itan kan ni, oju orun ni Ẹfunsetan gba de oju iku nigba ti iroyin miran ni wọn fun ni majele jẹ ni.

Sugbọn ta ba n sọrọ awọn obinrin takuntakun nilẹ Ibadan ati nilẹ Yoruba, itan ko lee gbagbe Ẹfunsetan Aniwura, tori o se iwọn to lee se lasiko tiẹ.

Awọn Iyalode to ti jẹ ni ilẹ Ibadan

Iyalode Subola, 1850-1867

Iyalode Efunsetan Aniwura, 1867-1874

Iyalode Iyaola, 1874-1893

Iyalode Lanlatu Asabi Giwa, 1894-1913

Iyalode Isale Osun, 1914-1917

Iyalode Ronilatu Ajisomo, 1917-1934

Iyalode Rukayat Awosa Akande, 1935-1948

Iyalode Abimbola, 1948-1961

Iyalode Adebisi Abeo, 1961-1974

Iyalode Wuraola Esan, 1975-1985

Iyalode Hunmani Alade, 1985-1995

Iyalode Aminatu Abiodun, 1995-2018