Nigeria swearing in 2019: Babajide Sanwoolu gba ọpa àṣẹ láti tukọ̀ Eko

Babajide Sanwoolu di gomina tuntun ni Eko

Ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣù kẹfà, ọdún 1965 la bí Babajide Olusola Sanwoolu tó ti jawe olubori ninu idibo ipinlẹ Eko.

O jẹ́ olùdíje fún ipò gómínà Ìpínlẹ̀ Eko lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, eyí tó jẹ́ pé ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni.

Ẹ̀kọ́

Fásitì Eko (UNILAG) ló ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ gboyè wọnlẹ̀wọnlẹ̀ (Surveying) nígba tó wà ní ẹni ọdún mẹ́tàlélógún ní ọdún 1988.

Láìpẹ́ rẹ̀ ni ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àgbà ìmọ̀ okòwò ni fásìtì kan náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó tún tẹ̀ síwájú láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ okòwò àti ìṣèjọba ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gígá wọ̀nyìí:

  • Kennedy School of Government
  • Lagos Business School
  • London Business School

Àwọn ibi tó ti ṣiṣẹ́

Sanwo Olu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe ní ilé ìfowópamọ́ Lead Merchant Bank láàrin ọdún 1994 sí 1997 gẹ́gẹ́ bíì akápò.

Lẹ́yin náà ni ó tún gbéra lọ ilé ìfowópamọ́ UBA gẹ́gẹ́ bí adarí owó lati òkèèrè.

Lẹ́yìn èyí ni ó lọ ilé ìfowópamọ́ First Inland Bank, èyí tí a mọ̀ sí First City Monument Bank báyìí.

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwoolu

Àwọn iléeṣẹ́ àdáni tí Sanwoolu ti ṣe adarí

Gomina tuntun ti ajọ INEC kede náà jẹ́ alága iléeṣẹ́ Baywatch Group Limited àti First Class Group Limited nígbà kan rí.

Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ayẹ̀wé owó wò fún Caverton Offshore Services Group Plc.

Àkọlé fídíò,

Àgbà ni Obasanjo, oun tó ń sọ yé e, ìjọba ni kó tají - Wale oke

Àwọn ipò òṣèlú tó ti dì mú rí:

Ọdun 2003 ni Sanwo Olu bẹ̀rẹ̀ òṣèlú nígba tí igbákejì gomina Ipinlẹ Eko nígbà kan rí Femi Pedro yàn án gẹ́gẹ́ bíi olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ àwọn iléeṣẹ́ àdáni.

Lẹyìn náà ni Gomina Ipinlẹ Eko lákòókò náà, BolaTinubu yàn án gẹ́gẹ́ bíi olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ àwọn iléeṣẹ́ àdáni lẹ́yìn tí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Pedro àti Tinubu.

Òun ni alága àkọ́kọ́ ìgbìmọ̀ tó ń ṣe àkóso Security Trust Fund Ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò,

Murphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó dìmú lẹ́yìn èyí rèé:

  • Kọmíṣọ́nà fún ètò ìsúná
  • Kọmíṣọ́nà fún ọrọ̀ ajé
  • Kọmíṣọ́nà fún ìdásílẹ̀ àtí ìtọ́ni

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Ní ọdún 2016, Gomina Akinwunmiu Ambode yàn án gẹ́gẹ́ bíi adarí iléeṣẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko tó ń ṣàkóso àwọn ilé kíkọ́.

Oluṣọla Sanwo olu lo gba aṣẹ lati bẹrẹ si ni tukọ ipinlẹ Eko ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun un, ọdun 2019.

Àkọlé fídíò,

Ìbádọ́gba nínú ìsèlú àti iṣẹ́ láwùjọ ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsóké