Climate Change: Àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́ta gba owó ìrànwọ́ iwádìí ìjìnlẹ̀

Arunma Otteh Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si ẹka iṣẹ ati iṣe ti ọmọ Naijiria ko tii maa moke tabi ko ipa ribiribi lagbaye

Awọn olukọ fasiti mẹta lorilẹ-ede Naijiria ni wọn ti gba owo iranwọ bayii fun iwadii imọ ijinlẹ lori ayipada ayika ati ojuọjọ.

Arunma Oteh.

Arunma Oteh ni igbakeji aarẹ banki agbaye, World Bank. Oun si tun ni akapo banki naa bayii.

Orukọ rẹ wa ninu iwe itan gẹgẹ bii ẹni ti o ṣe afọmọ ọja idokoowo lorilẹ-ede Naijiria lasiko ti o fi jẹ oludari agba fun ajọ ọja idokoowo Naijiria, SEC.

Fasiti orilẹ-ede Naijiria, to wa ni ilu Nsukka ni o ti kẹkọ jade. Oun naa pẹlu ṣiṣẹ diẹ pẹlu Banki idagbasoke ilẹ Afirika atawọn ajọ miran lagbaye ki wọn to yan an gẹgẹ bii oludari agba ajọ ọja idokoowo ní Naijiria ni asiko iṣejọba Aarẹ Umaru Musa Yaradua.

Awọn ọmọwe ti wọn ṣẹṣẹ fun Naijiria lorukọ tuntun ni agbaye:

Image copyright Alamy
Àkọlé àwòrán Ajọ iwadi ijinlẹ African Institute for Mathematical Sciences (AIMS) fun awọn ọmọwe naa ni owo iranwa iwaadi

Ajọ iwadi ijinlẹ African Institute for Mathematical Sciences (AIMS) fun awọn olukọ fasiti naa, Ọmọwe Daniel Akinyele, Ọmọwe Ayanṣina Ayanlade ati Ọmọwe Adanna Henri-Ukoha ni owo iranwọ naa pẹlu awọn Ọmọwe miran jakejado ilẹ Afirika bii Ọmọwe Lindani Ncube lati South Africa, Ọmọwe Timothy Dube lati Zimbabwe pẹlu Ọmọwe Muhire Innocent lati Rwanda.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ayẹwo to jina to si gbona girigiri ni wọn yan awọn mẹfa yii eyi ti ọpọ sọ pe o ṣafihan pe kii ṣe ninu iwa ibajẹ nikan ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n tayọ bikoṣe ninu awọn ohun amuyangan pẹlu.

Kii kuku ṣe awọn mẹta yii nikan ni ọmọ Naijiria ti o n da bi ẹdun, rọ bi owe lawujọ agbaye, ọpọ lo n tayọ lawọn ẹka bii imọ ẹrọ ati sayẹnsi, irinajo afẹ, karakata ati idokoowo lai yọ idaleeṣẹ silẹ ati bẹẹbẹẹ lọ sẹyin.

Diẹ lara wọn niyi:

Akinwumi Adeshina

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Owo iranwọ iwaadi ijinlẹ ti wọn gba naa yoo tubọ mu idagbasoke ba imọ nipa ayipada oju ọjọ ati iṣesi ayika

Akinwumi ni aarẹ banki idagbasaoke Afirika, African Development Bank, ADB bayii. O de ipo yii pẹlu iṣẹ takuntakun ti o gbe ṣe lasiko ti o fi wa nipo akoso lorilẹede Naijiria. Fasiti Ile Ifẹ ti o ti di fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ , OAU bayii ni o ti kẹkọ jade. Ipo minisita fun eto ọgbin labẹ iṣejọba aarẹ Goodluck Jonathan ni o wa ti wọn fi dibo yan an fun ipo aarẹ banki afirika naa.

Mohammed Barkindo:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ìròyìn ìwà ìbàjẹ́ ni ó ń s'aba máa jáde nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé

Laipẹ yii ni wọn yan an gẹgẹ bii akọwe ẹgbe ajọ awọn orilẹede to n wa epo rọbi lagbaye, OPEC yatọ si iriri rẹ lẹka epo rọbi, o ni iriri pupọ pẹlu ni ẹka ifowopamọ ati awọn ileeṣẹ idokoowo agbaye. Ni ọdun 2009 ni wọn yan an gẹgẹ bii Ọga agba ajọ epo rọbi lorilẹ-ede Naijiria, NNPC ki aarẹ Goodluck Jonathan to yọ ọ nipo lọdun 2010 ti o si pada si ajọ OPEC.

John Boyega:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ló ṣì ń dá bí ẹdun rọ̀ bí òwè nínú iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò.

John jẹ ara awọn elere itage ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n yọ ni agbo ere fidio agbelewo ni orilẹ-ede Amẹrika. Ilẹ Gẹẹsi ni o gbe nibẹ ni o si ti bẹrẹ ere itage ṣiṣe ni ileewe lati nnkan bi ọdun mẹjọ. Ki o to lu aluyọ pẹlu ipa ti o ko ninu ere gbajugbaja ni the Star Wars.

O kopa ninu fidio agbelewo ti wọn ṣe ninu iwe ilumọọka Half of a Yellow Sun ti gbajugba akọwe nni, Ngozi Adichie kọ. Ọrẹ lo si jẹ Damilọla Taylor, ọmọ Naijiria ti awọn eeyan kan yinbọn pa ni ilẹ Gẹẹsi ni ọdun 2000.

Hakeem Kae-Kazim

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ẹẸka bii imọ ẹrọ ati sayẹnsi, irinajo afẹ, karakata ati idokoowo lai yọ idaleeṣẹ silẹ ati bẹẹbẹẹ lọ ni awọn ọmọ Naijiria ti n tan bi oorun

Ilu Eko ni Hakeem gbe ni igba ewe rẹ ki o to lọ si ilu London fun ẹkọ nileewe ere itage Briston Old Vic Theater Shool. Lẹyin eyi lo si kopa ni awọn fidio agbelewo to gbajumọ lagbaye bii Hotel Rwanda, Pirates of the Carribean: At World's End ati X-Men Origins: Wolverine pẹlu 24 hours.

Oluyinka Olutoye

Image copyright Texas Children's Hospital

Dokita iṣegun ti o ṣe ohun ti ẹni kan ko ṣe ri ni Dokita Oluyinka Olutoye. Ohun ni dokita ti o ṣe iṣẹ abẹ fun oyun inu, ti o si tun gbe e pada si inu iya rẹ pada ki wọn to bii.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn dokita iṣegun kan ni ki arabinrin naa o ṣẹ oyun naa, Dokita Olutoye atawọn ẹmẹwa rẹ ni ileewosan Texas Children's Hospital ni ko si iṣoro bi obinrin naa ko ba dẹyẹsi ki wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un ki wọn gbe oyun inu rẹ jade ki wọn si ṣe iṣẹ abẹ fun oyun naa lati yọ jẹjẹrẹ ti o n daa lamu.

Lẹyin wakati marun un, Dokita Olutoye atawọn ikọ dokita ti o ko sodi pari iṣẹ abẹ naa wọn si da oyun yii pada si inu iya rẹ ki wọn to wa bii ni nnkan bi ọsẹ mejila lẹyin iṣẹ abẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'

Gbogbo agbaye ni okiki iṣẹ abẹ aramọnda yii kan de ti wọn si n pe ọmọ ti wọn bi naa ni ọmọ ti wọn bi ni igba meji ọtọọtọ.

Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ ni Oluyinka Olutoye ti kọkọ gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ iṣegun ati iṣẹ abẹ ki o to gba oke ọkun lọ lati lọ gba imọ kun imọ.

Nibayii oun ni Oludari agba ileewosan awọn ọmọ wẹwẹ ti Texas Children's Hospital lorilẹede Amẹrika.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCJ Gold: ẹ̀rù kọ́ka ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOmi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí