Europa: Arsenal, Chelsea gbáradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpele ìsọ̀rì tó kẹ́yìn

Awọn agbabọọlu Arsenal n yọ lẹyin ti wọn gba goolu wọle Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Arsenal ati Chelsea ti kógojá fún ìpele tí ó kàn nínú ìdíje Europa ti sáà bọ́ọ̀lù 2018/2019

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu kaakiri ilẹ Yuroopu yoo tun kan lu papa ni ọjọbọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ti o gbẹyin ninu abala isọri-isọri idije Europa ti saa ọdun 2018/2019.

Lara wọn ni awọn ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi bii Arsenal ati Chelsea.

Lootọ Arsenal ati Chelsea ti pegede fun ipele to kan, ṣugbọn awọn mejeeji ṣi n ja fun pipegede lati jawe olubori ninu isọri wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù parọ́ ikú mọ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ láti wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀

Arsenal yoo maa koju ikọ agbabọọlu FK Qarabag ni papa iṣire Emirates; nigba ti Chelsea yoo lọ ba MOL Vidi lalejo .

Olukọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, Maurizio Sarri ni ifẹsẹwọnsẹ naa "le pupọ lati gbaradi fun".

Amọṣa, o ni oun yoo gbe ikọ ti ko fi bẹẹ le pupọ kalẹ fun ifẹsẹwọnsẹ naa nitori ọna ti la fun wọn pe awọn yoo bori isọri naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lootọ Arsenal ati Chelsea ti pegede fun ipele to kan, ṣugbọn awọn mejeeji ṣi n ja fun pipegede lati jawe olubori ninu isọri wọn

"Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo le pupọ nitori pe ko si afojusun tabi ilepa to yanranti kan lori rẹ"

O fi kun un pe"Ifẹsẹwọnsẹ ti a gba ṣaaju eyi pẹlu ikọ agbabọọlu Vidi ti a bori pẹlu ami ayo kan si odo le pupọ nitori wọn di oju ile wọn daradara, o nira fun wa pupọ lati gba ayo wọ ile wọn."

Fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, olukọni ẹgbẹ agbabọọlu naa, Unai Umery ni oun ko tii lee sọ boyaMesut Ozil yoo kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nitori ẹyin ti o n dun un.

Amọṣa o ni Laurent Koscielny yoo kopa lẹyin ti o ti gbọn ara nu kuru ninu iṣoro iṣan ẹsẹ ti o n yọọ lẹnu.

Bakan naa lo ni Aaron Ramsey yoo kopa n inu ifẹsẹwọnsẹ naa.