Faṣọla: Kìí ṣe ẹ̀bi ìjọba àpapọ̀ tí o kò bá rí iná ọba lò

Faṣola Image copyright @fasola
Àkọlé àwòrán Faṣọla ni ki ẹnikẹni má ṣe da ẹ̀bi ru ijọba mọ

Oriṣiriṣi nkan lawọn ọmọ Naijiria ti n sọ lori ohun ti Faṣọla sọ nipa ina mọnamọna Naijiria lasiko yii.

Kíni Faṣọla wi nipa iná mọnamọna Naijiria lasiko Buhari?

Tó ò bá ri ina mọnamọna lo, kii ṣe ẹbi ijọba apapọ ni ọrọ ti awọn ọmọ Naijiria n ba minisita fun nkan amuṣagbara, ile gbigbe ati iṣẹ ode, Babatunde Fashọla, fà.

Fashọla ni iroyin sọ pe o sọ ọrọ yii nibi ipade ijiroro kan to waye lori ọrọ ina mọnamọna, Nextier Power Dialogue, lalẹ Ọjọru, nilu Abuja.

Fashola sọ fun awọn to wa nibi eto naa pe lootọ ni iṣoro wa lẹka nkan amuṣagbara, ṣugbọn o ni ki wọn o ranti pe kii ṣe iṣoro ijọba apapọ ti awọn araalu ko ba ri ina mọnamọna lo, paapa niwọn igba ti wọn ti sọ ẹka naa di ti aladani.

'Gbogbo dukia ileesẹ to wa fun nkan amuṣagbara ti wọn n lo fun amojuto ina mọnamọna ni iṣakoso to kọja ta ki n to de ipo. Nitori eyi, ka ma parọ fun'ra wa, kii ṣe ẹbi ijọba ni ti ẹ ko ba ri ina lo.''

Fashọla ṣalaye pe "ojuṣe kan ṣoṣo ti oun ni ni lati pese awọn ilana ti wọn yoo mu lo ati amojuto, bo tilẹ jẹ wi pe mi o le ri iṣoro ki n ṣe bi alairi i.''

Image copyright Getty Images

Àwọn ọmọ Naijiria fariga lori ohun ti minista sọ

Ina mọnamọna jẹ koṣee-mani fawọn eniyan lawujọ ọlaju. Yoruba ni ti ẹyin lohùn, to ba ti bọ, ko ṣee kó mọ́.

Awọn kan ran Faṣọla leti pe ina ọba wa lara awọn koko ti ijọba yii fi ṣe ipolongo idibo lọdun 2015. Lara wọn ni Senetọ Shehu Sanni to pe Faṣọla ni opurọ ni ikanni twitter rẹ pe:

Babatunde Fashọla sọ pe awọn olokoowo to ra ileeṣẹ ina mọnamọna ni ki awọn eniyan d'oju ibeere tabi ẹdun ọkan wọn lori airi ina lo kọ, kiiṣe oun gẹgẹ bi minisita tabi ijọba apapọ.

Awọn bii Banusọ n beere fun alaye lori ona ti ijọba ti gba ta ina ọba ati ọna pinpin ina mọnamọna.

Pupọ ninu awọn to n fesi si ohun ti Fashọla sọ loju opo Twitter sọ pe ki Fashọla ranti ọrọ to sọ l'ọ̀dun 2014 pe ''ijọba to ba mọ nkan to n ṣe yoo yanju wahala to n koju ina mọnamọna ni Naijiria laarin oṣu mẹfa pere.''

Awọn miran gbà pe kii ṣe Faṣola ti awọn mọ to tun ipinlẹ Eko ṣe lo n sọrọ bayii sawọn eniyan Naijiria.

Bakan naa lawọn miran ni:

Aimọ iye igba ni ijọba to wa ni iṣakoso ti sọ ni gbangba pe ipese ina mọnamọna ti dara si ju bi awọn ṣe ba a lọ, ṣugbọn ohun ti awọn araalu n sọ tako eyi.

Bi awọn kan ṣe n pariwo airi ina lo daada, ni awọn miran n polongo pe owo ti awọn ileeṣẹ amunawa n gba lọwọ awọn oniibara pọju boṣeyẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'