Nigeria Swearing in 2019: Seyi Makinde di gómìnà tuntun

Seyi makinde n se ibura g bi gomina tuntun ni Ọyọ

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kejila ọdun 1967 ni wọn bi Oluwaseyi Abiodun Makinde si idile oloogbe Pa Olatunbosun Makinde ati iyaafin Abigael Makinde ni agbo ile Aigbọfa Oja'aba, ilu Ibadan.

Seyi Makinde bẹrẹ ile iwe alakọbẹrẹ ni St. Paul Primary School, ko to re si ile iwe alakọbẹrẹ St. Michael Yemetu, mejeeji ni ilu Ibadan.

Ile iwe Girama ti Bishop Phillips Academy ni Monatan, Ibadan lo lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Oludije ipò Gómìnà labẹ asia PDP ní Oyo sọrọ nípa Ladoja

Ni ọdun 1985, o wọ ile iwe giga fasiti ilu Eko, nibi to ti gba oye Bachelor's degree ninu imọ ẹrọ, Electrical Engineering.

Makinde ṣe agunbanirọ ni ile iṣẹ epo Shell lọdun 1990, lati ibẹ lo ti bẹrẹ iṣẹ nipa biboju to oniruuru ẹka ile iṣẹ epo naa.

Oríṣun àwòrán, @SupportSeyi

Oniṣowo ni Ṣeyi Makinde, oloṣelu si ni pẹlu. O jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu imọ ẹrọ. O ti ṣiṣẹ ni ọpọlọpọ ẹka imọ ẹrọ ati awọn ile iṣẹ epo bẹntiroo ati afẹfẹ gaasi lorileede Naijiria ati loke okun. Bẹẹ naa si lo ka iwe kun iwe sii loke okun.

Ẹ́ni ọdun mọkandilọgbọn ni Seyi Makinde nigba to kọkọ da ile iṣẹ epo ati afẹfẹ gaasi aladani tirẹ silẹ lọdun 1997, lẹyin to ti ṣiṣẹ fun ọdun marun un nile ati lẹyin odi.

Gẹgẹ bi oludari ati alakoso ile iṣẹ epo, Makinde ti darapọ mọ ọpọlọpọ ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ ninu iṣẹ epo bẹntiroolù ati afẹfẹ gaasi lorilẹede Naijiria ati loke okun.

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Àkọlé àwòrán,

Oluwaseyi Makinde

Ni ti Oṣelu, Seyi Makinde ti du ipo aṣoju nile aṣofin fun ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Nigeria Peoples Party, ṣugbọn o bọ mọ ọ lọwọ si ọwọ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa lọhun, Kamoru Adedibu.

Makinde ko jẹ ki ijakulẹ rẹ fun igba akọkọ da omi tutu si i lọkan, o tun gbe apoti ibo lati ṣoju ẹkun idibo kan naa lọdun 2011 ṣugbọn nibi idibo abẹle lo ti fidi re'mi.

Lọdun 2014, Seyi Makinde kara bọ didu ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Oríṣun àwòrán, Oluwaseyi Makinde

Àkọlé àwòrán,

Day 20: Ìgbà mélòó ni Ṣeyi Makinde ti dupò rí? #BBCNigeria2019

Ni kete ti wọn pari idibo abẹle ni wọn ko fun un ni tikẹẹti 'a yan ọ gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ', sugbọn o bọ lọwọ rẹ si ọwọ oludije miran.

Ẹwẹ, Makinde o mikan, o tẹra mọ ipinu rẹ o si kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP lọ si ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP nibi tó ti dije gẹgẹ bii gomina ipinle Oyo lodun 2015 ṣugbọn nigbẹyin, ko bọ sii fun un.

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Àkọlé àwòrán,

Oluwaseyi Makinde

Lọdun 2017, amoju ẹrọ Makinde pada si ẹgbẹ oṣelu rẹ tẹlẹ, PDP; o ni kii ṣe tori anfani ti oun yoo jẹ loun ṣe dara pọ mo egbe PDP, bi ko se fun idagbasoke ipinle Oyo nipa wiwa ojutu si opolopo isoro to n doju ko ipinle naa.

Ni ojo kokandinlogbon osu kesan, odun 2018, Makinde jawe olubori gege bi eni ti yoo dije fun ipo gomina legbe oselu Peoples Democratic Party, ninu idibo gbogbo gbo ti odun 2019 nipinle Oyo.

Ibo 2,772 lo ni ninu idibo abele eyi to waye ni ilu Ibadan.