Mọ̀ síi nípa Yakubu tó wọ bàtà tí Jẹ́gà bọ́ sílẹ̀ ni INEC

Image copyright @inec
Àkọlé àwòrán Ẹni to ba dantọ lo le ṣeto idibo Naijiria ko kógo já

Oṣu karun un, ọdún 1962 ni wọn bi Mahmood Yakubu nipinlẹ Bauchi ni ariwa iwọ oorun Naijiria.

O lọ sile iwe alakọbẹrẹ Kobi ko to lọ si ile ẹkọ ikọni-niṣẹ olukọ laarin ọdun 1975 si ọdun 1980 nibi to ti gbegba oroke ni kilaasi rẹ ko to lọ si fasiti Ṣokoto to ti di ti Usman Danfodio bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionINEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo

Mahmood gbami ẹyẹ Waziri ti Ṣokoto lọdun 1985 nigba ti o jẹ akẹkọọ to dara julọ ninu ẹko nipa ìtàn oṣelu to ti ṣetan pẹlu ipele akọkọ. Oun ni o jẹ ọmọ ilẹ Hausa akọkọ ti yoo gbami ẹyẹ ipele kinni yii.

Image copyright @inec
Àkọlé àwòrán Ibeere ọpọlọpọ ni pe ṣe Mahmood to lati wọ bata Jẹga?

Ati ranmu gangan, kọ ṣeyin eekanna ni ọrọ aṣeyọri Mahmood.

O ri anfani owó iranwọ gbà loriṣiiriṣii lati fi kawe bii ti owo ẹkọ ọ̀fẹ́ tipinlẹ Bauchi ati Cambridge Commonwealth Trust Scholarship ni eyi to fi kẹkọọ gboye ikeji lori ọna ibaraẹniṣepọ lagbaye lọdun 1987 ati iranwọ to fi gba oye ọmọwe ni Oxford lọdun 1991 lọmọ ọdun mọkandinlọgbọn.

Opọlọpọ ami ẹyẹ bii ti Beit Fund Research Grant lo gba lasiko to n kawe nilu Ọba.

Yakubu Mahmood bẹrẹ iṣe olukọni ni fasiti Jos lọdun 1986 ko to lọ si Defence Academy ni Kaduna nibi to ti goke agba gba oye ọjọgbọn lọdun 1998.

Image copyright @inec
Àkọlé àwòrán Mahmood ti fawon eeyan Naijiria lokan bale pe, didun losan a so ninu idibo 2019 nitori INEC a ṣiṣẹ bo ti yẹ

O ṣe adari ati alakoso ẹka eto ẹkọ lorisiirisii ni eyi to ti ni iwe apilẹkọ to le ni aadọta.

Mahmood ṣiṣe kaakiri bii nio ajọ TETFund, ETF, PRESID ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ohun to jẹ ọjọgbọn Mahmood logun ni ayipada rere si awọn ẹka eto ẹkọ ni Naijiria ni eyi to n sọrọ le lori lasiko to n kopa ninu apero CONFAB tọdun 2014 ti aarẹ Goodluck Jonathan pè.

Image copyright @inec
Àkọlé àwòrán Abajade iṣẹ ti ajọ INEC ba ṣe ninu idibo 2019 yii lo maa sọ ibi ti Naijiria n lọ

Oṣu kẹwaa, ọdun 2015 ni Buhari yan Ọjọgbọn Mahmood Yakubu to gba iṣẹ lọwọ Amina Zakari ti aarẹ Buhari yàn gẹgẹ bii adelé alaga ajọ eleto idibo INEC leyin ti Ọjọgbọn Attahiru Jega lọ lẹyin idibo 2015.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn.

Wọn yan Amina Zakari gẹgẹ bi adele lọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun 2015 lẹyin ti Jẹga pari ọdun marun un rẹ gẹgẹ bii alaga ajọ INEC.

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu gbe iyawo, o si bi ọmọkunrin meji ati ọmọbinrin meji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKinni wọn n pè ni oṣupa déjé ní kíkún?
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obinrin jẹ amuludun'