Àwọn nkan tó jẹyọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò f'áwọn tó fẹ́ di igbákejì àárẹ

oludije
Àkọlé àwòrán Àwọn marun un ti wọn figagbaga sọ ohun ti wọn ni lọkan fun Naijiria ni 2019

Ipá kò rajà; ipá kò tàá ni ọ̀rọ̀ ijiroro awọn oludije igbakeji aarẹ bá de

Eruku sọ lasiko ti awọn oludije fun ipo igbakeji aarẹ marun un pejọ sibi ifọrọwerọ ti ajọ Nigeria Election Debate Group (NEDG) ati Broadcasting Organizations of Nigeria ṣagbatẹru rẹ l'Abuja lọjọ Eti

Awọn oludije to kopa ni:

Yẹmi Osinbajo - All Progressives Congress (APC)

Peter Obi - People's Democratic Party (PDP)

Umma Getso - Youth Progressives Party (YPP)

Alhaji Abdulganiyu Galadima - All Congress Party of Nigeria (ACPN)

Khadijah Abdullahi-Iya - Alliance for New Nigeria (ANN)

Diẹ lara awọn nkan ti wọn sọrọ le lori niyii:

Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn oludije

Bi awọn kan ṣe n binu pe wọn ko pe gbogbo oludije, ni wọn n ri ariwisi sawọn ti wọn kopa, loju Ọmọyẹle Ṣoworẹ:

Loju àwọn kan bii Omoba Abodunrin Siwoniku lori ikanni BBC Yoruba, wọn gbà pé ibi gbogbo la ti n kadiyẹ alẹ ni ọrọ iwa ibajẹ yii jẹ.

Àkọlé àwòrán Obi n ṣafiwe ọrọ, Ọṣinbajo naa n fesi, lori ona abayọ siṣoro Naijiria

Loju Fayoṣe to jẹ gomina àná ipinlẹ Ekiti, Peter Obi ti PDP lo fakọyọ julọ pẹlu ọgbọn siṣoro eto ọrọ aje Naijiria lasiko yii ni eyi ti awọn miran fun un lesi pe irọ ló ba de.

Koko ti ọpọlọpọ n jiyan lé lori lẹyin ijiroro naa ni ọrọ Obi pe, o ko le tilẹkun ṣọọbu maa fojoojumọ le olè kiri ni eyi ti Ọṣinbajo fun un lesi pe, ko ni si ọja kankan mọ ni ṣọọbu to ba gba olè laaye lati maa jale lọ

Bi àwọn bii Balogun Adewunmi ṣe n gboriyin fun Obi fun akaye rẹ lori ikanni BBc Yoruba naa ni àwọn bii Adeyanju Wadudu Olaoluwa n ki Ọṣinabjo pe o mọ esi ọrọ

Àkọlé àwòrán Awon eeyan kan n kigbe pe ebi n pa ara ilu laisko yii

Loju ọpọ eniyan Obi ati Oṣinbajo lo fakọyọ ju ti wọn si gba awọn oludije igbakeji to ku lati tun ero wọn pa bi o ti yẹ ko le han pe wọn kun oju oṣuwọn.

Ero àwọn mii bii Sotunde Olasile ati Shogbola Temmy Tayo lori ikanni BBC Yoruba naa ṣotọọtọ lori ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria pe:

Àkọlé àwòrán Ebi kii wọnu ki ọrọ mii wọo lero ọpọlọpọ

Tambuwal ati awọn ẹgbẹ PDP gboriyin fun eeyan wọn pe omọ to to ran niṣẹ ni Peter Obi nigba ti APC naa yombo Ọṣinbajo pe akọni to to gbangba sun lọye ni

Awọn mii n gba imọran pe iwọnba ni ki awọn ọmọ Naijiria ba ara wọn ja lori ayelujara mọ nitori ẹni aàmọ̀rí

Ni ipari ijiroro naa, bi awọn kan ṣe sọ pe Obi n parọ ninu awọn odiwọn to mẹnuba naa ni awọn miran gboriyin fun ọrọ ikadii Obi ti PDP nigba ti awọn mii tabuku bi oludije ẹgbẹ YPP ṣe n polongo Ojọgbọn Moghalu dipo ko sọ ohun to ni fun ilu. Bakan naa lawọn mii n sọrọ lodi si ọrọ Ọṣinbajo ti APC pe o ṣaa n tako iṣejọba PDP fun ọdun mẹrindinlogun ni dipo ko mẹnuba aṣeyọri ti wọn ba ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOmi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Diẹ lara awọn kókó to jẹyọ ninu ijiroro naa:

a) Ti ede aiyede ba waye laarin yin ati aarẹ ti ẹ n ṣe igbakeji fun, ki lẹ o ṣe?

Lori eyi, Ọṣinbajo sọ pe ipo igbakeji aarẹ jẹ olugbaninimọran agba fun aarẹ.

Bakan naa lo jẹ ẹni ti aarẹ le fun ni oriṣiriṣi ojuṣe lati ṣe, ṣugbọn eyi ni i ṣe pẹlu bi aarin wọn ba ṣe ri, ati ifinutan ara ẹni.

Ẹwẹ, Ọṣinbajo sọ pe ipo igbakeji aarẹ gba ọpọlọpọ suuru, nitori pe oriṣiriṣi ilana ni aarẹ yoo gbe jade, iwọ si le ma faramọ wọn.

Lori ibeere yii, aṣoju PDP, Peter Obi sọ pe oun ko ni wahala tabi ikunsinu pẹlu ẹnikẹni ri ninu iṣejọba, nitorina ieu nkan bẹ ko le aye laarin oun ati Atiku Abubakar.

Àkọlé àwòrán Àwọn nkan tó jẹyọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò f'áwọn tó fẹ́ di igbákejì àárẹ

Bakan naa lo sọ pe ojuṣe igbakeji aarẹ ni lati mu ajinde ba eto ọrọ aje orilẹede.O gbọdọ le da iṣẹ́ silẹ

Igbákejì ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ọjọgbọ́n Yemi Osinbajo tún dẹbi ru ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party lóri ètò ọ̀rọ̀ ajé tó dẹnukọlẹ̀.

Lẹ́yìn ti wọn bií lóri ìdí tí gbogbo ìdóko-òwò Nàìjíríà ò ṣe kọjá ìdá mẹ́rìndínlógun láti ọdún mẹwàá sẹ́yìn yàtọ́ sí bí South Africa àti China ṣe ni ìdàgbàsókè

Osinbajo ní" mo rò pé ohun tó jọ ara wọn láàrin orílẹ̀-èdè méjèèji ti ẹ dárúkọ ni pé wọn ni ohun etò amúlùdùn tó gbópọn. Orílẹ̀-èdè Nàìjírìà ní ọdún mẹ́rìndílogún sẹ́yìn ní pé ìyà ohun amúludùn ti jẹ wa sẹ́yìn.

b) Njẹ o yẹ lati maa san owo iranwọ lori epo bẹtiro?

Isoro kan to n fa idiwọ fun ẹka dida iṣẹ silẹ ni aisi awọn akanṣe iṣẹ. A nilo akanṣe iṣẹ.

Nkan gboogi to n fa iṣẹ ati oṣi l'orilẹede Naijiria ni iwa ibajẹ gẹ̀gẹ̀ bi ile ifowopamọ̀ agbaye ṣe sọ. Ti a ko ba pa iwa ibajẹ run, a ko ni le ṣe ohunkohun.

Àwọn nkan tó jẹyọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò f'áwọn tó fẹ́ di igbákejì àárẹ

Àkọlé àwòrán Àwọn nkan tó jẹyọ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò f'áwọn tó fẹ́ di igbákejì àárẹ

Lori ọrọ owo iranwọ epo, Ọṣinbajo sọ pe kiiṣe ohun to buru ni lati san an, sugbọn iwa jibiti laarin awọn alagbata epo lo ba eto naa jẹ.

''Ni kete ti a ba yọ owo ori iranwọ epo, nkan yoo wọn. A gbọdọ faramọ sisan owo iranwọ epo fun igba diẹ, to ba ya, ao dawọ rẹ duro.

Ti a ba fẹ ẹ yọ, a gbọdọ kọkọ bi awọn ọmọ Naijiria pe ''eelo ni wọn le ra epo bẹtiro?''

Image copyright Getty Images

Lori eyi, oludije fun igbakeji aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Peter Obi, sọ pe Naijiria gbọdọ fi opin si sisan owo iranwọ epo fun awọn alagbata. Ẹwẹ, Obi sọ wipe gbigbogun ti iwa ibajẹ kiiṣe ara ilana iṣejọba.

Bakan naa ni awọn oludije yoo ku bi Umma Getso ti ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party, eto naa gbọdọ wa sopin nitori a ko gbọdọ tẹsiwaju lati maa san owo fun aikoju oṣuwọn.

------------------------------------------------------------------------------------------

Lori boya ki orilẹede Naijiria bu ọwọ lu iwe ajumọṣe fun eto ibudo idokowo kan ṣoṣo fun awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika, Continental Free Trade Zone agreement, Ọṣinbajo sọ wipe ojuṣe ijọba to mọ nkan to n ṣe ni ko ṣe agbeyẹwo awọn nkan to yẹ, ki o to buwọlu iru adehun bẹ.

Ohun to sọ yii na lo wọpọ ninu ohun ti awọn oludije to ku sọ. Gbogbo wọn gbagbọ pe iru igbesẹ bẹ n fẹ ikiyesara ati agbeyẹwo anfaani ti yoo ṣe orilẹede Naijria.

Ni tiẹ, aṣoju ẹgbẹ oṣelu Youth Progressives Party, YPP, Umma Getso, o sọ pe iru eto naa kiiṣe igbesẹ to yẹ fun Naijiria lati gbe.

-----------------------------------------------------------------------------------------------