'Àṣà ìgbéyàwó Yorùbá gbàràdí ní Kenya'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Omi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Oriṣii igbeyawo lo wa nílẹ̀ Yorùbá.

Ìran Yorùbá ni igbeyawo oloruka ti ṣọọsi to jẹ fun ọkọ kan ati aya kan, bakan naa ni ìran Yorùbá maa n ṣe igbeyawo ti mọṣalaṣi to faaye gba ọkọ kan lati ni to aya mẹrin ti apá rẹ ba kaa.

Ni afikun ìran Yorùbá maa n ṣe igbeyawo alarede ni Kootu to wa fun aya kan ati ọkọ kan pẹlu igbeyawo ti aṣante ti ko wọ́pọ̀ mọ́ laye ode oni. Koko to pa gbogbo igbeyawo yii pọ ni pe, ẹbi ọkọ maa n wa ṣe idana pẹlu ẹbi iyawo ti wọn yoo ko ohun idana bii owó orí, iṣu, epo, iyọ, ẹja, aṣo ati awọn nkan miran wa.

Laye atijọ, ọmọ Yorùbá máa n fe ara wọn ni ṣugbọn ohun gbogbo ti yatọ laye ode oni.

Awọn ọmọ Yorùbá ti n fẹ iran miran ni Naijiria bii Hausa, Igbo, Nupe, Fulani ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bayii, ọmọ ti aye bí ni ayé n pọ̀n, bi ọjọ ṣe n gori ọjọ́ ni nkan n yipada sii ti ọmọ Yorùbá n fẹ iran miran lati ilẹ okeere bii apẹẹrẹ ti igbeyawo toni ti BBC Yorùbá mu wa.

Ọmọ Yorùbá ni Diran Oloyede to lọ gbe Jacqueline Jumah ọmọ Kenya niyawo ti wọn si sọ wọn di ọkan.

Àṣà, ìṣe, ounjẹ ati aṣọ iran Yorùbá loriṣii ni eyi to n ṣe ipolongo iwa rere Naijiria lo jade nibi igbeyawo Diran ati Jacqueline ni Kenya.

Agbada, buba, sokoto, iro, buba, gele, pẹlu ijo oniruuru ni awọn ẹbi, ara, ati ọrẹ Diran fi gbe ogo iran Yorùbá ga nibi eto igbeyawo naa.

BBC Yorùbá gbà pé ko si ibi ti ogidi ọmọ Yorùbá ko ti le fọn rere aṣa ati iṣe Yorùbá si rere.