Ondo Kidnapping: Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ ni ọ̀rọ̀ àwọn ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Ondo

Agbebọn
Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìgbà ni ìjínigbé ti wáyé ní ojú ọ̀nà ìlú Ọ̀wọ̀ sí Ìkàrẹ́-Àkókó.

Laiti pe ọsẹ kan ti awọn ajinigbe ji eniyan mẹẹrin ni ipinlẹ Ondo, wọn tun ti ji eniyan mẹta miran gbe lọjọ Abamẹta to kọja.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph sọ fun akọroyin BBC Yoruba, pe eniyan mẹta ni awọn ti wọn ji gbe lootọ, ṣugbọn ''ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i le sọ boya Fulani lo ji wọn gbe nitori pe a ko ti i ri wọn'' tako iroyin to jade pe awọn fulani daran-daran lo ji wọn gbe.

Bakan naa lo sọ ijinigbe ati iwa ọdaran gbogbo kiiṣe ọrọ ẹya tabi ẹsin.

Àkọlé fídíò,

Ile isẹ ọlọpaa n gbe Ọrẹkunrin Khadijat rẹlẹ ẹjọ ni Ọjọ Aje

"Ọwọ wa tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹjọ ni bi ọsẹ meji sẹyin, ko si si ẹya Fulani kankan lara wọn. Awọn mẹjọ naa si ti wa ni ihamọ nitori ọrọ wọn ti de ile ẹjọ."

Gẹgẹ bi ohun ti Joseph sọ, ọkan lara awọn mẹta ti wọn ji gbe jẹ olukọ ni ileewe gbogbonise Rufus Giwa to wa ni ilu Ọwọ nipinlẹ Ondo.

Ọna to lọ si ilu Ipele nitosi Ọwọ ni wọn ti ji olukọ naa gbe.

Àkọlé àwòrán,

Laipẹ yii ni awọn ọlọpa tu awọn inu igbo kan ti igbagbọ wa pe awọn ajinigbe naa fi ṣe ibuba wọn ni oju ọna ti ọrọ kan

Awọn meji to ku ni wọn ji gbe ni ilu Ọsẹ loju ọna to lọ Ọwọ si Ikarẹ-Akoko, nipinlẹ Ondo bakan naa lasiko ti wọn n rinrinajo.

Ṣugbọn ohun to daju nipe ileeṣẹ ọlọpa ko ni duro tabi fọwọ lẹran ti ọwọ yoo fi tẹ awọn amokunṣika naa.

Ti kọmisana ọlọpa Olugbenga Adeyanju si ti ṣe ọpọlọpọ ipade pẹlu awọn ọba, ọdẹ ati awakọ nibi ti iṣẹlẹ yii ti maa n ṣẹlẹ lati ran iwadi lọwọ.

Igba akọkọ kọ niyii ti iṣẹlẹ yii n waye. Nibi ọsẹ kan sẹyin ni awọn ajinigbe gbe eniyan mẹẹrin; oṣiṣẹ ileewosan Federal Medical Centre to wa nilu Ọwọ, ati olukọ ileewe gbogboniṣe Rufus Giwa.

Awọn mẹta gba ominira 'lẹyin ti awọn mọlẹbi wọn san owo itusilẹ, nigba ti eniyan kan si padanu ẹmi rẹ si akata awọn ajinigbe.

Eyi si mu ki awọn dokita ileewosan naa maa dunkooko lati bẹrẹ iyanṣẹlodi tijọba ko ba wa nkan ṣe si ijinigbe to n waye ni gbogbo igba loju ọna naa.

Àkọlé fídíò,

'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'

Bakan naa ni awọn ajinigbe gbe ọdọmọbinrin kan nilu Akurẹ lẹnu irinajo rẹ si ilu Ondo ninu oṣu Kọkanla, ko to o di pe awọn ọlọpa doola rẹ nigba ti olobó ta wọn. Ọwọ wọn si tẹ afurasi meji.

Ẹwẹ, lori ijinigbe to n waye, ẹka ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo ṣe iwọde lọjọ kejila, oṣu Kejila pe ki ijọba o kede nkan o fararọ lori ijinigbe.

Ninu oṣu Kọkanla bakan naa ni wọn ji alaga ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress ADC), Bisi Ogungbemi, ati awọn oloye ẹgbẹ mẹta mi i, lara eyi ti oludije fun ipo sẹnetọ kan Jide Ipinsagba wa.

Wọn ji wọn gbe loju ọna Ọwọ si Ikarẹ-Akoko lasiko ti wọn n pada si ilu Akurẹ lati ilu Ikarẹ-Akoko lẹyin ipolongo oṣelu.

Laipẹ yii ni awọn ọlọpa tu awọn inu kan to wa ni oju ọna marosẹ Ọwọ si Ikarẹ ati eyi to lọ lati Akurẹ si Ọwọ nibi ti igbagbọ wa pe awọn ajinigbe naa fi ṣe ibuba wọn.

Awọn ọmọ ileeṣẹ ologun naa gbe iru igbesẹ yii ninu oṣu Karun un, ṣugbọn ko pẹ ti wọn dawọ duro ni iroyin sọ pe awọn ajinigbe naa tun bẹrẹ iṣẹ ibi wọn.

Ṣe ka sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣiṣẹ to ni?

Lori ibeere yii, Fẹmi Joseph sọ pe ''idojukọ kan pataki taa n ni ni pe, nitori pe ipinlẹ Ondo paala pẹlu ipinlẹ to pọ, bi a ṣe n mu ọpọlọpọ wọn ni awọn mi i tun n ṣiṣẹ.

Bi a ṣe n ge wọn lọwọ ni wọn n bọruka. Ọna naa gun de ipinlẹ Kogi. Oju kan ṣoṣo kọ lo ti n ṣẹlẹ.

Eyi kii ṣe lati ṣe awawi, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni pe a n ti n lo ọna miran lati ṣiṣẹ."

Ibo ni ileeṣẹ ọlọpa ba iṣẹ de?

"Ọpọlọpọ nkan lati n ṣe bayii lati ri i pe ọrọ ijinigbe di afisẹyin ti eegun n fiṣọ. Ati fi kun awọn ọlọpa to n duro loju ọna. Bakan naa ni a ti pe awọn miran ti kii ṣe ọlọpa mọra lati ran wa lọwọ.

Ohun ti a fẹ lati ọdọ araalu ni pe ki wọn maa ta wa lolobo, gbadura fun wa, ki wọn si mu suuru diẹ fun wa, ao ṣiṣẹ naa bi iṣẹ

A ko mọ boya awọn ajinigbe ti kan si awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe, nitori ileeṣẹ ọlọpa kii lọwọ si. Idi ni pe ọpọlọpọ ọdaran yoo maa lo anfaani pe ileeṣẹ ọlọpa faaye gba sisan owo fun ajinigbe lati maa ṣiṣẹ ibi.

Ti a ba fun ẹnikan lowo loni, ẹlomii yoo tun wo awokọṣe naa lati ji ẹlomiran gbe.

A si maa n rọ awọn araalu lati fi to wa leti ti awọn ajinigbe ba kan si wọn, ṣugbọn o ṣeni laanu pe mọlẹbi awọn ti wọn ba ji gbe kii ṣọ fun wa lasiko ti wọn ba kan si wọn tabi san owo itusilẹ."

Àkọlé fídíò,

Gbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Àkọlé fídíò,

''Ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣì n sọnù ni orilẹ̀-ede Burundi'