Àwọn òṣìṣẹ́ ilé aṣòfin Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ iyànṣẹ́lódì

Aworan ile asofin agba Naijiria Image copyright @NgrSenate
Àkọlé àwòrán Awọn asofin ṣi n ba iṣẹ lọ ni ile aṣofin lalai si iranlọwọ awọn oṣiṣẹ ile aṣofin

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé aṣòfin Nàìjíríà tí mú ìlérí wọn ṣẹ láti gbegi dina iṣẹ ni ile náà pẹlu bi wọn ti ṣe bẹrẹ iyanṣẹlodi lọjọ Ajé

Lọsẹ to kọja ni wọn leri lati da iṣẹ gbogbo duro lori bi awọn alaṣẹ ile aṣofin naa ko ti ṣe san owo oṣu wọn.

Iroyin to tẹwa lọwọ so pe niṣe ni awọn oṣiṣẹ naa yan iṣẹ lodi ni ile asofin ohun lọjọ aje tii ṣe ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun 2018.

Àkọlé àwòrán Awọn oṣìṣẹ́ fẹ̀hónú hàn níle ìgbìmọ̀ Aṣofin

Saaju ni wọn ti gbe awọn ìgbésẹ̀ kan to fi mọ bi wọn ti ṣe ṣe iwọ́de ìfẹ̀hónú hàn láti dí ìgbòkègbòdò ilé ìgbìmọ̀ àsṣòfin lọ́wọ́ lọjọ́ kerin àti ọjọ́ kẹjọ oṣù kejila, ọdún 2018.

Iyanṣẹlodi ko da iṣẹ duro

Tóhun tí iyanṣẹlodi náà, àwọn aṣòfin tí kéde orúkọ àwọn ọmọ àjọ tí yóò mójú tó ètò gbogbo nílé aṣòfin Nàìjíríà.

Ikede orukọ awọn ọmọ ajọ naa ti Aarẹ ile asofin Bukola Saraki kede ni wọn fi sita loju opo Twitter ile asofin lọjọ aje kannaa ti awọn oṣiṣẹ ohun da iṣẹ silẹ.

Ara iredi iyansẹlodi awọn oṣiṣẹ ile asofin ni wi pe awọn ko ri ẹtọ awọn gba nipaṣẹ owo osu ati ajẹmọnu ti o tọ si awọn .

Igbagbo wọn si ni wi pe iyanṣẹlodi naa yoo ṣe idiwọ fun iṣẹ awọn asofin eleyi ti yoo mu ki ọrọ naa ni iyanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'

Ko ti daju boya awọn alaṣẹ yoo wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ to wa nile yi ṣugbọn bi nnkan ti ṣe n lọ yi,o le ṣe akoba fun iṣakoso eto gbogbo nile asofin paapa julọ aba isuna ti Aarẹ Buhari fẹ gbe wa si iwaju ile asofin lọjọru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá