ASSU Strike: Ìpàdé ASUU àti ìjọba tún forí sánpọ́n

ipade Image copyright other
Àkọlé àwòrán ijọba kò ṣetan lati wọn ọn kun, ASUU naa ko fẹ gbaa ni aabọ lori ọrọ iyanṣelodi olukọ fasiti

Ipade to n waye laarin ẹgbẹ olukọni ile ẹkọ giga fasiti lorile-ede Naijiria Asuu ati ijọba Naijiria tun ti fori sanpọn.

Lọjọ Aje nilu Abuja la ti gbọ wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ ASUU binu jade kuro ninu ipade ti o yẹ ki wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba ti Minisita fun ọrọ iṣẹ ni Naijiria Chris Ngige le waju wọn.

Image copyright @ngige
Àkọlé àwòrán Ọrọ n bá ọrọ bọ

Chris Ngige to jẹ minista fun ọrọ iṣẹ ni Naijiria ni tootọ ni ijọba ṣe ipade pẹlu ASUU ni eyi ti wọn ti jọ n sọ asọyepọ lori awọn nkan ti ASUU n fẹ.

O ni ki awọn le jọ wa ọna abayọ naa loun ṣe pe ipade naa ati pé abọ iṣẹ ti a fun ẹnikọọkan nile iṣẹ ijọba ni a ṣẹṣẹ n to pọ ki a le mọ ọna abayọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Ni ipari o ni idi ti awọn ko ṣe yanju ọrọ naa ni pe oun ki onikaluku ri ọjọ diẹ lati wo awọn akọsilẹ naa wò ṣaaju keresimesi.

O fi idaniloju han pe awọn olukọ a fopin si iyanṣẹlodi na laipẹ ati pe awọn akẹkọọ a wọle nibẹrẹ oṣu kinni ọdun 2019.

O ni oun yoo ṣe ipade pẹlu minista fun eto inawo lati yanju ohun gbogbo ti ASUU n beere nitowo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Gbogbo igbiyanju lati ba alaga ASUU sọrọ lo jasi pabo nitori o ni oun ko ni ohunkohun lati sọ ki Ngige jabọ ohun to ṣẹlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá
Image copyright Twitter

Ko ti daju oun to mu ki awọn olukọni naa binu jade ninu ipade ohun ṣugbọn saaju ipade naa la gbo wi pe ọgbẹni Ngige ti sọ wi pe ohun ni ireti wi pe ọrọ yoo ni iyanju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionASUU Strike: Bí àwọn kan se dunnú, làwọn kan fajúro

Awọn olukọni ile ẹkọ fasiti Naijiria ti dẹgun le iyansẹlodi ọlọjọgbọrọ lati ọjọ kẹrin osu kakanla ọdun yi yi.

Ohun to mu wọn gun le iyansẹlodi naa ni awọn nnkian koko mẹta ta ti ri owo osu wọn ti wọn ni ko munadoko to,atunto ati atunṣe awọn ile ẹkọ to fi mọ ajẹmunu awọn olukọni naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'