Fayemi: Gbèsè tí mo bá nílẹ̀ ni kò jẹ́ kí n ti yan kọmíṣọ́nà

Ọmọwe Fayẹmi ni ere ọmọde ni igbesẹ ijọba fayose lati fofin de oun Image copyright Fayemi /twitter
Àkọlé àwòrán Ijọba ipinlẹ Ekiti f'ofin de Fayemi fun ọdun mẹwaa losu to koja

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi sọ pe ko si owo lati yan kọmiṣọna kankan fun ipinlẹ naa.

Fayẹmi la gbọ wi pe o sọ ọrọ yii lasiko eto oloṣooṣu kan to ti maa n ba awọn araalu sọrọ lori amohunmaworan.

O ṣalaye pe idi pataki ti oun ko ṣe ti i yan awọn kọmisana, to fi mọ awọn olubadamọran pataki ti yoo ba iṣakoso rẹ to ti pe oṣu meji ṣiṣẹ bayii, ko ṣẹyin ki oun le lanfaani lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'

Lati igba to ti di gomina ipinlẹ Ekiti l'ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwa, Akọwe fun ijọba ipinlẹ, olori awọn oṣiṣẹ, ati Akọwe oniroyin agba fun ijọba nikan ni wọn jọ n dari ilu.

Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ, Akọwe Ikede fun Gomina Fayẹmi, Yinka Oyebọde, sọ pe awọn gbese ti ijọba Fayẹmi ba nilẹ, paapa ajẹsilẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ, ni ko ti i jẹ ki anfaani ṣi silẹ lati yan kọmisana.

Igbagbọ ijọba ni pe owo oṣu awọn kọmisanna ati awọn amugbalẹgbẹ to ku yoo tun mu ki gbese ti ijọba o pọ si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYorùbá gbà pé òrìṣà bí ìyá kò sí!

Oyebọde sọ pe gomina Fayẹmi ro o wi pe ki oun duro lati pawo wọle diẹ, ko to o yan wọn.

O ṣalaye pe ijọba ti n gbe awọn igbesẹ bi i ṣiṣe atunṣe si awọn nkan to n pawo wọle fun ijọba; Ikọgosi Warm Spring ati awọn ileesẹ ijọba mi i. Bakan naa ni ijọba n gbero lati pe awọn ileeṣẹ ti owo ori to gọbọi ati awọn ilana ijọba ti ko fararọ, ti le kuro l'Ekiti, pada, to fi mọ ṣiṣe iṣẹ agbẹ aladanla.

Image copyright Kayọde Fayẹmi
Àkọlé àwòrán Ẹwẹ, ijọba n gbero lati ṣe afihan ipo ti apo aṣuwọn ijọba ipinlẹ Ekiti wa l'ọjọ to ba ṣe ajọyọ ọgọrun ọjọ lori oye.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCJ Gold: ẹ̀rù kọ́ka ba ìyá mi nígbà ti mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìjà jíjà

Ati ti ijọba ba ri gba lara awọn owo ti ijọba apapọ jẹ ipinlẹ Ekiti. Gbogbo owo yii ni wọn fẹ ẹ kopọ lati yanju awọn gbese to wa lọrun ijọba.

O sọ pe lati mu ki eyi ṣeeṣe, o ni ijọba Ekiti ti n ba awọn to yẹ sọrọ.

Ẹwẹ, ijọba n gbero lati ṣe afihan ipo ti apo aṣuwọn ijọba ipinlẹ Ekiti wa l'ọjọ to ba ṣe ajọyọ ọgọrun ọjọ lori oye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlápinni: Kò sí ẹni to fẹ́ kọ́kọ́ kọ́ iṣẹ́ òṣèré bíi ti àtẹ̀yìnwá
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGbogbo ènìyàn ló wọ agbádá ikú, ẹni tó kàn lẹnìkan kò mọ̀

Related Topics