LASEMA: kí àwọn ará ìlú tó ba kẹ́fin oníṣẹ́ ibi tètè máa jáde sọ̀rọ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIná sọ lẹ́yìn táwọn ajépo gbé bẹ́ àgbá epo l'Abule Egba

Ọpọlọpọ padanu mọto lataari ọpa epo rọbi to jona l'Abule Ẹgba nipinlẹ Eko loru oni.

Ajọ LASEMA ti wọn n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko ni àwọn ti gbe gbogbo awọn to fi ara pa ninu iṣẹlẹ naa lọ fun itọju nile iwosan.

Ogbẹni Tiamiyu Adeṣina to jẹ ọga agba ajọ LASEMA ni awọn oniṣẹ ibi ti wọn n ji epo rọbi lati inu ọpa epo lo ṣokunfa ina to ṣẹ naa.

O ni ko sẹni kankan to sọ ẹmi rẹ nu ninu iṣẹlẹ ọhun ṣugbọn ọpọlọpọ ile lo jona ni Awori ni Abule Ẹgba ti ọpọlọpo si n ṣofọ awọn nkan ti wọn padanu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBuruji Kashamu: Èmi ṣì ni olùdíje PDP ní Ìpínlẹ̀ Ogun
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRepublic of Benin: ìtàn tó bí abẹ́sàn án kọjá bẹ́ẹ̀!

Ọga agba LASEMA gba awọn ara ilu niyanju lati maa tete sọrọ jade ni kete ti wọn ba ti kẹfin ohunkohun ladugbo wọn.

O ni awọn ti ri oriṣii itọni ati awọn igbese to yẹ ki ajọ awọn agbofinro gbe ni eyi ti o fi ṣeeṣe lati fopin siru iṣẹlẹ yii nibi ifọrọwanilẹnuwo ti awọn ti ṣe pelu awọn ara Abule Ẹgba.

Image copyright @trafficbutter
Àkọlé àwòrán ọpọlọpọ mọto, ọjà ati nkan amuludun lo jona ni Abule Egba nidaji
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeun Kuti: Fela ló n pọ́n gbogbo òǹkọrin Afrobeat lagbaye

Related Topics