Àwọn olùgbé Maiduguri ìṣoro ni àpọ̀jù iná mọ̀nàmọ́nà ń da àwọn láàmú

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iná mọ̀nàmọ́nà tí a ní tí pọ̀jù Grindin

Àwọn olùgbé iluu Maiduguri tí ṣe olú ìlùú Borno ti farígá, wọn ní àwọn ò nílò iná mọ̀nàmóna oní wákàtí mẹ́rìnlèlógun mọ bíkòṣe pé kí wọn pada sí wákàti méjìlá ti wọn ń fún àwọn tẹ́lẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùgbé Maikduguri ṣe sọ mímú iná wá dede ń ṣe àkóba fún àpò àwọn nítorí owó gọbọi ní àwọn Yola Electricity Distribution Company (YEDC) ń fún àwọn nítori iná náà kò wúlò.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, Ibrahim Suleiman tó bá akọ̀ròyìn NAN sọ̀rọ̀ sàlàyé pé kíì ilé iṣẹ́ YEDC pada sí iná wákàtí méjìlá nítori pé iná náà kò wúlò ní àsìkò tí àwọn bá lọ sí ibiṣẹ́, sùgbọn owó ti YEDC ń mú wa ti pọ jú agbára ohun lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSeun Kuti: Fela ló n pọ́n gbogbo òǹkọrin Afrobeat lagbaye

Esther Chukwuma sàlàyé pé oun tí ó ti ń san ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àbọ̀ náírà tẹ́lẹ̀ di ẹni tó ń san ẹgbẹ̀rùn mẹ́rìnlá fún iyé owó kan náà.

Nínú àwọn tó fẹ̀hónú han sàlàyé pé ilé yàrá kan tún ń san ẹgbẹ̀rúndínlógún náírà, èyí sì túmọ sí ìyànjẹ .

Wọn rọ àwọn ilé iṣẹ́ náà láti ṣe atúnṣe tó to nítorí iná wákàti mẹ́rìnlelógún