'Òjíṣẹ ní ifá jẹ fún àwa Yorùbá'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Cotonou Museum: Àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Yorùbá di àpéwò ní Porto-Novo

Jakejado orile aye ni aṣa ati iṣẹṣe Yoruba ti jẹ oun amuyangan.

Ki aṣa yii ma ba a parun, awọn ọmọ Kaaro o jiire, yala nijọba tabi aladani, maa n ṣe agbekalẹ ibudo ise nkan isembaye lọjọ si, lati fi gbe awọn atọka aṣa Yoruba larugẹ.

Ọkan lara awọn ibudo yii ni ti ibudo isẹmbaye to wa ni ilu Porto Novo, Cotonou ni orileede Benin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikọ BBC Yoruba ṣe abẹwo si ibudo ise nkan isembaye lọjọ si naa, ti oludari ibudo naa, alagba Yusufu Amuda Adepeju ti ṣe alaye nipa awọn nkan ti o wa ni ile naa.

O salaye fun BBC Yoruba pe, awọn n gbiyanju ki awọn nnkan aṣa Yoruba mase parẹ.

Ninu awọn nnkan ti wọn ko si ibudo ise nkan isembaye lọjọ si naa, lo ni awọn nnkan to tọka si awọn orisa Yoruba, to fi mọ Ogun, IIfa ati Esu wa.