APC Kwara: Abdulrahman ṣì ni olùdíje wa fún ipò Gómìnà

AbdulRahaman AbdulRasaq Image copyright APC KWARA
Àkọlé àwòrán Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ lo ṣe idibo abẹnu to gbe Abdulrahaman Abdulrazaq wọle gẹgẹ bi oludije ipo Gomina

Akowe ipolongo apapọ ẹgbẹ APC, Lanre Issa Onilu ti tako idajo ile ẹjọ giga kan nilu Ilorin to ni igbimọ ẹgbẹ labẹ akoso Ishola Blogun Fulani ni ojulowo igbimọ ẹgbẹ.

Issa Onilu fi ọrọ rẹ to tako idajọ yi sita ninu atẹjade kan.

Lọjọru ni ile ẹjọ giga kan nilu ilorin fi idajọ sita eleyi to tunmọ si wi pe oludije ti idibo abẹnu Ishola Balogun sakoso rẹ ni o tọ lati du ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ APC.

Onilu salaye pe ẹgbẹ APC le Ishola Balogun Fulani ati awọn ọmọ igbimọ kuro ninu ẹgbẹ lẹyin iwadi to safihan wi pe o n gbe igbesẹ to tako ẹgbẹ.

Àkọlé àwòrán Akọroyin nigba kan ri ni yoo ṣoju APC dupò gomina Kwara

Fun idi eyi o ni ,awọn oludije ti igbimọ amuseya ṣe idibo abẹnu fun ti wọn si jaweolubori ni ojulowo oludije ẹgbẹ APC ninu ibo 2019.

''A rọ awọn ara ilu Kwara lati ma ṣe korẹwẹsi ọkan ki wọn si gbaruku ti wa ninu ilakaka ati tu Kwara ninu oko amunisin''

Bi a ko ba gbagbe,ikọ Ishola Balogun Fulani ti saaju ṣeto idibo abẹnu eleyi to gbe AbdulWahab Omotose Kayode jade gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nínu idibo abẹnu ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Kwara.