Budget 2019: Wo àwọn aṣíwájú àgbáyé míràn táwọn èèyàn dẹ́yẹsí lágbayé

Buhari ni ile aṣofin apapọ Image copyright Ahmad Bashir
Àkọlé àwòrán Diẹ lara awọn to ti ba irufẹ itiju ati ariwo idẹyẹsi bayii pade ni Donald Trump, Theresa May, Jacob Zuma ati George Bush

Idarudapọ ti ko kere lo waye nigba ti aarẹ Muhammadu Buhari tọ awọn aṣofin apapọ lọ lati gbe aba eto iṣuna orilẹede Naijiria ọdun 2019 kalẹ niwaju wọn fun agbeyẹwo.

Amọ ṣa, iran kọ wiwo nigba ti aarẹ yoo fi pari agbekalẹ rẹ pẹlu bi o ṣe di sinima agbelewo ninu eyi ti awọn aṣofin kan ti n dẹyẹsi aarẹ ti awọn ti o ṣe tirẹ pẹlu si n yin in.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kii ṣe ojuti diẹ ni ọrọ yii gbe kalẹ fun aarẹ nitori lai ṣi aniani eyi ni igba akọkọ ti aarẹ kan lorilẹede Naijiria yoo dojukọ irufẹ idẹyẹsi ati ojuti bẹẹ lasiko ti wọn n gbe irufẹ aba iṣuna bẹẹ kalẹ niwaju awọn aṣofin apapọ.

Àwọn agba bọ wọn ni a ko ri iru eyi rii, ẹru la fi n da bara ẹni; Aarẹ Buhari kọ ni aarẹ akọkọ ti yoo foju wina atako awọn eeyan rẹ ti wọn yoo gbe ka ori pepele itiju kaakiri agbaye.

Diẹ lara awọn to ti ba irufẹ itiju ati ariwo idẹyẹsi bayii pade niwọnyii:

Donald Trump:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ kii si n lẹyin Aarẹ Donald Trump ti Amẹrika; Bi o ṣe n dẹyẹsi awọn ọmọ orileede rẹ lawọn naa n da pada fun un

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump kii ṣe ajeji si idẹyẹsi; paapaa lati igba ti o ti di aarẹ orilẹede Amẹrika ni ọdun 2016. ọpọ igba ni o si maa n forigbari pẹlu awọn oniroyin. Ọkan lara igba ti wọn dẹyẹ sii rẹ ni ita gbangba naa ni asiko kan ti o lọ si ibi ipadeeto ọrọ aje agbaye, World Economic Forum, (WEF) ni Davos nigba ti o fi ẹsun iroyin ofege kan awọn oniroyin.

Ẹrin ati ọpọ idẹyẹsi ni awọn ero ti o n wo o ifọrọwerọ rẹ lọjọ naa fi pade rẹ.

George Bush:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari kọ ni aarẹ akọkọ ti yoo foju wina atako awọn eeyan rẹ ti wọn yoo gbe ka ori pepele itiju kaakiri agbaye

Lasiko ti o fi n ba awọn oniroyin sọrọ ni aafin olotu ijọba orilẹede Iraq to wa ni ilu Baghdad, aarẹ orilẹede Amẹrika nigba naa pẹlu foju wina irufẹ idẹyẹsi to fa idoju nlanla kaakiri agbaye nigba ti akọroyin kan, Muntadhar al-Zaidi ju bata ẹsẹ rẹ lu aarẹ George Bush.

Igba meji ọtọọtọ ni arakunrin yii ju bata lu aarẹ ilẹ Amẹrika ti oun pẹlu si yẹẹ nigba mejeeji ọhun.

Okiki iṣẹlẹ yii kan kaakiri agbaye ti ọpọ si rii gẹgẹ bii itiju fun odindi aarẹ orilẹede Amẹrika.

Afihan idẹyẹsi ati ikorira ni aṣa jiju bata lu eniyan ni aṣa awọn larubawa.

Theresa May:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn aṣofin kan dẹyẹsi aarẹ, awọn ti o ṣe tirẹ pẹlu si n yin in niwaju ile aṣofin apapọ

Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi pẹlu ti ni ipin tirẹ ninu irufẹ idẹyẹsi bayii.

Ọrọ igbesẹ lati fa ilẹ Gẹẹsi jade kuro ninu ajọ orilẹede Yuroopu, EU eleyii ti wọn da pe ni BREXIT lo n fun un ni ẹfọri julọ bayii.

Amọṣa diẹ lara awọn asiko ti wọn ti dẹyẹsi rẹ pẹlu ariwo ṣiọ ṣiọ ni igba ti o farahan nibi ajọdun Edinburgh Festival Fringe.

Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi naa lọ wo awọn akọrin Soweto Gospel Choir ti wọn n kọrin ni olu ilu orilẹede Scotland gẹgẹ bii ara ajọdun nla naa.

Ṣugbọn ni kete ti o gunlẹ nibẹ bayii ni ariwo hee, hẹẹ ti bẹrẹ pẹlu oniruuru idẹyẹsi.

Jacob Zuma:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Afihan idẹyẹsi ati ikorira ni aṣa jiju bata lu eniyan ni aṣa awọn larubawa

Lasiko ajọyọ iranti Nelson Mandela ti wọn ṣe ni ilu Johannesbourg ni awọn eeyan to wa nibẹ ti pariwo idẹyẹsi le Zuma lori lẹyin ti wọn ti kigbe ẹyẹ nigba ti wọn pe orukọ aarẹ amẹrika nigba naa, Barack Obama.

Lootọ ni wi pe irufẹ iwa yi a ma mu iriwisi ọtọọtọ wa ṣugbọn ko daju wi pe awọn ara ilu ko ni ye wu iru iwa bayi si awọn olori wọn.

Idi ni wi pe ofin fi aye silẹ fun isọrọ gẹgẹ bi ẹtọ ọmoniyan.

Ohun to wa ku ni ki onikalulku lo ẹtọ yi lọna ti ko fi ni koja ofin to fi aaye gba wọn.