Adams Oshiomole: Buhari ló lè gba Naijiria ní oko ẹrú

Adams Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán,

Alagba gbogboògbò fún ẹgbẹ́ òsèlú APC ti rọ àwọn ará Nazarawa láti di ìbò wọn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Alagba gbogboogbo fun ẹgbẹ oselu APC, Adams Oshiomole ti ni Ọlọrun ko ni jẹ ki ẹgbẹ oselu PDP pada si ipo lorilẹede Naijria.

Oshiomole to sọ eyi ni Nazarawa, wi pe ọdun mẹrindinlogun ti PDP fi wa nipo ni wọn fi ba ilẹ jẹ, ti wọn jẹ ilu run.

O ni Aarẹ Buhari nikan lo lee tun orilẹede yii se, ti yoo si da gbogbo ikolọ ti awọn asebaje ti kolọ pada.

Alagba gbogboogbo fun ẹgbẹ oselu APC naa wa fikun wi pe ọdun mẹta ko to lati fi yi igba pada lorilẹede Naijiria.

Amọ, ni ọpọ igba ni ẹgbẹ alatakọ PDP ti ma n sọ wi pe isejọba awọn daraju igba ti Aarẹ Buhari Muhammadu.