Ìpèníjà ojú kò dí Ademola lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́gboyè

Ìpèníjà ojú kò dí Ademola lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́gboyè

Onkọwe itan agbelẹkọ ni ṣugbọn ko riran lati le ka iwe to ba kọ.

Awokọṣe ni Ademola jẹ fun ọpọ eeyan to ni ipenija oju ṣugbọn oju rẹ ri too ki o to kawe gboye.

Ademọla sọ fun BBC nipa bi oun ti ṣe banujẹ nigba ti oju oun fọ.

''O dabi igba ti aye kọ ẹyin si mi ni.Inu mi ko dun.Mo ma n sunkun ni gbogbo igba''

Iriran rẹ ti ko lọ geere jẹ ipenija paapa julọ pẹlu awọn olukọni ti ko ba kaanu ipenija ti o ni.

''Olukọni kan ti sọ fun mi ri wi pe ko yẹ ki n wa laarin awọn ti ko ni ipenija ara kankan. o ni ile iwe awọn to ri bi temi lo yẹ ki n lọ''

Toun ti idẹyẹ si ti o ri Ademola ko ko irẹwẹsi ọkan ti o si ni erongba lati tẹsiwaju pẹlu ẹkọ rẹ ti agbara ba wa.

''Igbaniwole si ile ẹkọ nilẹ gẹẹsi ti mo ri ṣi wa nilẹ sugbọn mi o ri eeyan ti a ranmilọwọ lọ ka iwe naa ni ilẹ Gẹẹsi.''

Ọmọ ọdun mẹẹdọgbọn ni Ademọla