Logo Benz: Ìtanijí ni orin wa wà fún, Ẹ má ká wa lọ́wọ́ kò -Olamide

Aworan Olamide

Oríṣun àwòrán, Olamide/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Gbajugbaja ilumọka olorin takasufe ni Olamide

Igbe Olamide ati Lil Kesh lo gbẹnu awọn ọmọ Naijiria loju opo Twitter bayii.

O ṣeeṣe ki ẹ ma beere wi pe kini wọn ṣe

Ọlọpa ko ka igbo mọ wọn lọwọ tabi ibọn ṣugbọn lọdọ awọn ololufẹ orin takasufe,wọn ti da ọran kabiti.

Ọrọ inu orin tuntun kan ti wọn pe akọle rẹ ni Logo Benz lo n dagboro ru o.

Awọn ọmọ Naijiria gbo orin naa sugbọn kaka ki wọn gboriyin fun wọn lori orin tuntun naa,iriwisi ọtọọtọ lo ba de.

Loju opo Twitter awọn kan ko tilẹ pẹ ọrọ sọ pe orin naa gboriyin fun pipa eeyan lati fi ṣe ogun owo tabi wiwa ọna ẹburu lati ni owo eleyi ti awọn eeyan mọ si ''yahoo plus''

Ọrọ naa le ma bi awọn kan ninu ṣugbọn Olamide fun ara rẹ ti jade soju opo Twitter rẹ lati slaye pe oun ko ri nnkan to buru ninu orin naa.

O ni ohun to n ṣẹlẹ lawujọ ni oun n sọ ko siyẹ ki awọn eeyan ma ka awọn olorin lọwọ ko

Irori Wilson Israel ati ti Chinex papọ pẹlu ti Olamide.

Lọdọ wọn orin lasan lo kọ, o si ṣe pataki ki awọn eeyan gbo ẹkọ ti orin naa n kọ wọn

Awọn kan tun mu Fela Anikulapo wọ inu ọrọ yi.

Ọrọ iru orin ti awọn olorin asiko yi n kọ jẹ eleyi ti awọn ara ilu ma n mẹnu baa nigbakigba ti orin to ba ṣe bi ẹni yatọ ninu ẹkọ to kọ tabi bi wọn ti ṣe ṣe fidio rẹ.

Bi a ko ba gbagbe laipe yi ni iriwisi waye lori fidio orin Falz to pe akọle rẹ ni 'This is Nigeria'

Fidio orin naa to ṣe afihan awọn ọmọ obinrin to n jo Shaku Shaku pẹlu Hijab mu inu bi awọn ẹgbẹ Musulumi kan ti wọn ni orin naa tabuku ba ẹsin awọn.