TraderMoni: Igbákejì ààrẹ Osinbajo ní owóòyá TraderMoni kìí ṣe owó ìbò rírà

Osinbajo n ba Ọlọja kan sọrọ

Oríṣun àwòrán, AAAjimobi

Àkọlé àwòrán,

Oṣinbajo ní ó dín díẹ̀ ní mílíọ́nù kan àbọ̀ oníṣòwò tó ti jàǹfàní ètò owóòyá náà

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo ti pariwo sita pe owo iranwo fawọn ọlọja ati oniṣowo ti wọn pe ni 'TraderMoni' eleyii ti ijọba apapọ n pin kaakiri awọn ọja bayii kii ṣe fun rira ibo awọn araalu.

Ọpọ awọn onwoye, paapaa awọn ẹgbẹ alatako, ni wọn ti ke ibosi sita lori owo naa pe adọgbọn fi owo tu oju awọn ọlọja ki wọn lee dibo ni.

Oṣinbajo ni igbesoke aye awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaa awọn oniṣowo kekeke, ni owo TraderMoni wa fun.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Àkọlé fídíò,

'Mo ti gba kádàrá lórí bí Ọlọrun ṣe dá mi'

O ni awọn ọta oniṣowo ni wọn n pe owo naa ni owo raborabo.

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo

Àkọlé àwòrán,

Osinbajo ni awọn aṣofin apapọ buwọ lu owo naa

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn aṣofin apapọ buwọ lu owo naa ki ijọba apapọ to bẹrẹ pinpin rẹ kaakiri.

Igbakeji aarẹ ni owo naa kii ṣe owo ọfẹ nitoripe ẹka banki idaṣẹsilẹ, BOI kan wa ti o n mojuto nina ati gbigba pada wọle owo naa.

Oríṣun àwòrán, yemi osinbajo

Àkọlé àwòrán,

O ni awọn ọta oniṣowo ni wọn n pe owo naa ni owo raborabo

O ni aarẹ Buhari lo ti kọkọ bẹrẹ irufẹ eto bayii ni ilu rẹ ki o to de ipo aarẹ pẹlu ajọ kan eyi ti o n ṣeto ẹyawo alabọde fun awọn oniṣowo kerejekereje bi alakara atawọn okoowo miran.

O fi kun un pe o din diẹ ni miliọnu kan abọ eeyan ti wọn ti janfani eto owooya na.