Election 2019: Afẹ́nifẹ́re pín nítorí Buhari àti Atiku

Àkọlé fídíò,

Election 2019: Afẹ́nifẹ́re pín nítorí Buhari àti Atiku

Lati ọjọ pipẹ wa ni awọn agba Yoruba ti maa n ko ipa ti o jọju ninu ilana eto oṣelu ti ilẹ Yoruba yoo tọ.

Eyi tẹ siwaju pẹlu ipa pataki ti oloogbe Oloye Awolọwọ pẹlu ẹgbẹ ọmọ oduduwa to yirapada di ẹgbẹ Oṣelu Action group ko ninu idagbasoke oṣelu ilẹ Yoruba titi de ori Afẹnifẹre ati NADECO to jija gbara fun iṣejọba tiwantiwa.

Ko si jẹ ohun tuntun lati ri awọn ẹgbẹ aṣiwaju ilẹ Yoruba bii Afẹnifẹre, Igbimọ agba, OPC ati bẹẹbẹẹ lọ lati dide kede ohun ti wọn wo pe o yẹ ni ṣiṣe fun ilẹ Yoruba ni irinajo oṣelu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn nigba ti ẹgbẹ kan ba tun ti n tako ara rẹ lori ọna ti wọn fẹ tọ tabi fẹ ki Yoruba tọ lasiko oṣelu kan tabi omiiran, o n fẹ amojuto.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni oun ti buwọlu idapada sipo aarẹ fun aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yẹmi Oṣinbajo ninu ibo 2019.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Oloye Biọdun Akin-Faṣae lo kede eyi lẹyin ipade kan eyi ti o waye laarin awọn aṣoju ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ mẹfa ilẹ Yoruba lorilẹede Naijiria ni Gbọngan awọn lọbalọba ni ile ijọba nilu Ibadan.

Oríṣun àwòrán, @atiku

Àkọlé àwòrán,

Atiku ni igun ẹgbẹ Afẹnifẹre kan n tẹle

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni ọna itẹsiwaju ni oloye Awolọwọ to da ẹgbẹ naa silẹ maa n tọ, idi niyi ti awọn si fẹ fi tẹlẹ aarẹ Buhari nitori pe "o n sa ipa rẹ bi o ti mọ"

Amọṣa ohun ti o wa n ṣe ọpọ onwoye ni kayefi ni bi ẹgbẹ Afẹnifẹre yii kan naa ti ṣe kede ni ọsẹ diẹ sẹyin pe Atiku Abubakar to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn n ba lọ.

Ṣugbọn igun Afẹnifẹre to fi atilẹyin han fun Atiku Abubakar ti ṣalaye pe ẹgbẹ afẹnifẹre kan ṣoṣo ni o wa, Alagba Faṣọranti si ni olori ẹgbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Nǹkan ti rí bákan lẹ́gbẹ́ Afẹ́nifẹ́re báyìí pẹ́lú bí àwọn àgbà ẹgbẹ́ náà ṣe pínyà lórí àtìlẹ́yìn wọn fún Ààrẹ Buhari ti APC àti Atiku ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun Afẹnifẹre, Yinka Odumakin ni awọn oloṣelu ni awọn to korajọpọ lati fi atilẹyin wọn han fun Buhari ati Oṣinbajo kii ṣe Afẹnifẹre.

Gẹgẹ bi o ṣe wi, lẹyin oloye Fasanmi, ko si eyikeyi ninu awọn to ṣe ipade ni ilu ibadan ti o wa ninu ẹgbẹ naa.

Nibi ọrọ de duro yii, ibeere ti o n gba ẹnu ọpọ bayii ni pe, ewo gan an ni Afẹnifẹre ninu awọn mejeeji yii ati pe ewo gan an ni ki Yoruba o tẹle ninu wọn?