Obìrin kògbérégbè mẹ́ta nínú òṣèré Yorùbá

Lola Idije

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lola_Idije

Oríṣìríṣi àwọn òṣeré ló wà nínú àwọn òsèré sinimá àgbéléwó tí wọ́n sì ń kópa ọlọ́kan ò jọ̀ kan níbẹ̀.

Ṣùgbọ́n àwọn obìnrin kan wà tí wọ́n máa ń ṣe ipa ẹni tí kò gba ìgbàkugbà nínú eré.

Ọ̀kan lára àwọn òṣèré yìí ni Toyin Afolayan ti ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Lọla Idije.

Idijẹ ti pọẹ́ nínú ere sinimá Yorùbá, nínú eré náà ló sì ti rí ìnagijẹ rẹ̀.

Eré Obìnrin Àsìkò tí olóògbé Alade Aromire ṣe ni Toyin Afolayan ti rí ìnagijẹ rẹ̀ tíi ṣe Lola Idijẹ.

Idijẹ ṣe ìyá ìta tí kò gbàgbàkugbà nínú eré náà tí àwọn okùnrin sì mọ̀ ọ́ sí èyí.

Obìnrin náà ṣì ń kópa nínú àwọn eré sinimá àgbéléwò Yorùbá ni ọlọ́kan-ọ̀-jọ̀-kan.

Àkọlé fídíò,

'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Ó ti pẹ́ tí Sola Sobawale tí ń ṣe iṣẹ́ sinimá àgbéléwò. Ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Awada Kẹríkẹrì lábẹ́ àṣẹ àgba òṣèré, Adebayo Salami.

Bẹ́ẹ̀ náà ni òṣere náà ti kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ní iléeṣẹ́ amóhùnmáwòran NTA láì gba owó.

Gbajúgbajà òṣèré náà ti kópa nínú àwọn orísíríṣí eré bíi Asẹwo to re Mecca, Ohun Ọkọ sọ mi da, Asewo Kano àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣùgbọ́n tòun ti pé kò kìn ín gba ìgbàkugbà nínú eré, Sobowale ṣàlàyé fún BBC pé òun kìí ṣe ènìyàn tó burú.

Ó ṣe àfikún pé gbogbo nǹkan tí òun ń ṣe lórí eré ìtàgé kìí ṣe ìwà òun ni.

Oríṣun àwòrán, Mide

Ọ̀kan nínú àwọn Kògbérégbè láàrín àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ obìnrin tí wọ́n ń ṣe sinimá àgbéléwò Yorùbá ni Mide Funmi Martins Abiodun tó jẹ́ ọmo fún olóògbé Funmi Martin, ó sì jé aya fún òṣèré Hafeez Owo.

Mide náà ti kópa nínú àìmọye eré tó ti hùwà kògbérégbé gẹ́gẹ́ bí obìnrin.

Lára àwọn eré tó ti kópa ni Abami Eda, Ibeji Gbajumọ, Mama Iyawo Ika, Pregnancy Test, Owo ni koko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.