Yemi Alade: Bí a bá ní ìdí nlá bàa ní, kó sí ẹni tí kò rẹ́wà

Tiwa Savage ati Yemi Alade

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage/Yemi Alade/ Instagram

Àkọlé àwòrán,

Ija ti pari

Ija to waye lori Twitter laarin gbajugbaja akọrin Tiwa Savage ati Yemi Alade jọ bi ẹni pe o ti pari.

Fun bi wakati meloo kan lori ayelujara lawọn mejeeji n tahun si ara wọn lori ọrọ idi nla.

Yemi Alade fi ọrọ sita loju opo Twiiter lati tọrọ aforijin.

Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz

Àkọlé fídíò,

Yemi Alade Promo

Ninu ọrọ rẹ o ni oun fẹ ki awọn obinrin gbogbo mọ iyi ara wọn ati wi pe ko si ẹni ti ko rẹwa laaye tirẹ

''ati ẹni tirin,ati ẹni sanra,bo ni idi nla,bo ni,gbogbo wa la rẹwa''

Tiwa Savage ko ti fẹsi si ọrọ yi sugbọn awọn obinrin miran ti gbosuba kare fun Yemi Alade fun pe o wu iwa yi

Ija bum bum,ere lasan abi ootọ

Lọjọ ẹti lawọn olorin mejeeji naa Tiwa Savage ati Yemi Alade bẹrẹ ija lori ẹni ti idi rẹ tobi julọ laarin wọn.

Yemi Alade lo kọkọ fi ọrọ sita pe ki Tiwa Savage ye ma paro tan awọn eeyan pẹlu bi o ti ṣe n ṣe afikun idi rẹ ninu aworan.

Kiakia ni Tiwa Savage naa da esi pada fun

Awọn ololufẹ awọn ol;orin mejeeji ko gbeyin ti awọn naa si n fi ọrọ sita lori ija bum bum ohun

Awọn kan tilẹ ni ainiṣe lo n da awọn to n sọ ọrọ nipa idi nla laamu.