Union Bank: Àwa la ni owó tí EFCC gbà ní pápákọ̀ òfúrufú Enugu

AWORAN OWO DOLA

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ko ti daju ibi ti ọrọ yi yoo kangu si

Ile ifowopamọ Union Bank ti figbe sita pe awọn lawọn ni owo ti ajọ EFCC gba lọwọ awọn arakunrin meji kan ni papakọ ofurufu Akanu Ibiam nilu Enugu.

Wọn ni awọn okunrin naa n ba awọn gbe owo naa ni ati wi pe ko si ohun to buru ninu rẹ

Loju opo Twitter wọn ni wọn fi ikede yi si

Saaju lọjọ ẹti ni EFCC kede wi pe awọn mu awọn arakunrin meji kan ti wọn fura si wi pe wọn ṣe fayawọ owo.

Ninu ọrọ ti wọn fi sita loju opo Twitter, wọn fi hastag #MoneyLaundering si iwaju ọrọ wọn eleyi to tọka si wi pe owo naa ki ṣe owo etọ.

Efcc sọ ninu ọrọ wọn wi pe awọn arakunrin naa jẹwọ pe ile ifowopamọ kan lawọn n ba gbe owo naa ati wi pe o ti to ọdun mẹfa ti awọn ti n ba awọn ile ifowopamọ to loruko gbe iru owo bẹ.

''Won ni o ti pe ẹmẹrin tawọn ti gbe iru owo bẹ lọdun yi.''

Ko ti daju boya ile ifowopamọ naa yoo gbe Efcc lọ ile ẹjọ lati gba owo wọn ṣugbọn iṣẹlẹ yi ti mu iriwisi ọtọọtọ wa lori Twitter

Bi awọn kan ti ṣe n da Efcc lẹbi lawọn kan ṣe kayefi nipa bi ile ifowopamọ a ṣe tun ma gbe owo wọ baalu lati ilu kan si omiran