Ìkíni kú oríire ti ya bo Funke Akindele àti ọkọ rẹ̀ JJC Skillz

Oríṣun àwòrán, funke akindele
Gbajugbaja oṣere tiata Funke Akindele ti ọpọlọpọ n pe ni Jenifa ti di iya ibeji bayi, to ba jẹ pe ootọ ni awọn ikinni oriṣiriṣi to gba ori afẹfẹ lati aarọ ọjọ Abamẹta.
Bo tilẹ jẹ pè oun funra rẹ ko ti i sọrọ lori Twitter tabi Instagram lati sọ wipe ootọ ni oun bimọ lorilẹede Amerika, awọn ọrẹ rẹ ti n ki oun ati ọkọ rẹ Abdul Rasheed Bello ti aye mọ si JJC Skillz pe wọn ku ori ire.
Japheth Omojuwa wa lara awọn to ki ku ori ire.
Bẹẹ naa ni Reuben Abati to jẹ agbẹnusọ aarẹ ana, Goodluck Jonathan fi iroyin naa sori atẹ Twitter rẹ pee Akindele ti bimọ ni tootọ.
Oṣere tiata Mercy Aigbe ati sọrọsọrọ Toke Makinwa naa wa lara awọn to ba dunnu fun iroyin ayọ yii.
Oríṣun àwòrán, Mercy Aigbe/Instagram
Oríṣun àwòrán, Toke Makinwa/Instagram
Kinni ibimọ Akindele ṣe jẹ ọrọ nla laarin awọn ololufẹ rẹ?
Ni deede ọdun mẹta sẹyin ni wooli kan nilu Eko, Olagorioye Faleyimu ti ijọ Mountain of Blessing and Miracle ni o lè ma ri ọmọ bi.
Oríṣun àwòrán, Mountain of Blessing and Miracle Church of Christ
Wooli Faleyimu sọ nigba naa wipe ti ko ba ṣe awọn akanṣe adura kan, ko ni ri ọmọ bi titi to fi maa jade laye.
Ni ọdun 2017, wooli naa tun ni oun ko kabamọ pe oun ri "iran" yii. 2017 kan naa ni iroyin tan kaakiri wipe, Akindele loyun ṣugbọn o ti padanu rẹ, ni ọpọlọpọ ba n daro wipe boya "iran" wooli naa ti n wa si imuṣẹ ni.
Wooli yii ti ri awọn iran kan sẹyin. Ni ọdun meelo kan sẹyin lo sọ iran wipe awọn eekan oloṣelu kan bi Bola Tinubu yoo ku, ṣugbọn wọn ṣi wa laye bayii.
Àwọn ìròyín mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:
Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London