NLC: Gbogbo òṣiṣẹ ló n fẹ́ ilọsiwaju Naijiria

awọn oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Owó oṣu ti oṣiṣẹ n beere fun ko pọju

Ẹgbẹ NLC kede pé ìwọ́de ni wọn yoo fi ṣide iyanṣẹlodi naa ni 2019.

Nibi ipade apapọ oloye ẹgbẹ ajọ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ni wọn ti fẹnuko pe ti ijọba Buhari ba kọ̀ lati san ẹkunwo owo oṣu ti awọn oṣiṣẹ n jà fun lo fi ṣeeṣe ki nkan má ni ṣenu ire lọdun tuntun.

Wọn ni ẹgbẹrun naira lọna ọgbọn to jẹ odiwọn owó oṣu to kere julọ ti awọn n beere fun ko pọju rara Ojú ń kán wa, a fẹ́ gba àfikún owó osù tuntun- NLC.

Egbe awọn osiṣẹ ati ijọba ti ṣe ọpọlọpọ ipade sẹyin Ojú ń kán wa, a fẹ́ gba àfikún owó osù tuntun- NLC pẹlu iwọde ati iyanṣelodi Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ so ìyanṣẹ́lódì rọ̀ ti wọn fi kilọ fún ijọba pe ọwọngogo ni nkan ti onikaluku n rà lọja lasiko yii NLC: A ò ní dìbò wa fún àwọn gómìnà ọ̀tá òṣìṣẹ́

Ọgbẹni Ayuba Wabba to jẹ aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria ati Peter Ozo-Eson to jẹ akọwe ṣalaye pe ni gbogbo olú ilu ipinlẹ kọọkan ni Naijiria ni ìwọde naa a ti waye pẹlu Abuja.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Àkọlé fídíò,

Àwa ò fún ìjọba ní gbèdéke láti sanwó wa- ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Atẹjade ti wọn fi sita ni gbogbo oṣiṣẹ ati onikarakata lẹgbẹ kọọkan ni wọn jọ maa ṣe iwọde naa.

Wọn ni o jẹ ohun to bani lọkan jẹ pe ijọba Buhari kọ lati ṣe ohun to yẹ lati ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla ti awọn igbimọ tẹẹkoto ti jabọ fun Aarẹ Buhari pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni wọn fenuko le lori.

Wọn ni o jọniloju pe aarẹ Buhari tun le sọ fun awọn aṣofin pe oun tun fẹ ṣẹṣẹ gbe igbimọ tuntun kalẹ lati ri si ọrọ owo oṣu tuntun naa lasiko to n gbe iṣuna 2019 wa siwaju ilé.

Egbẹ oṣiṣẹ ni àwọn gba pe ko yẹ ki ọrọ igbimọ ṣi wa ninu ọrọ owo oṣu yii mọ.

Atẹjade naa fidi ẹ mulẹ pé igbese ijọba yii fihan pé ọrọ awọn oṣiṣẹ, ẹbí oṣiṣẹ ati àwọn eniyan Naijiria ko jẹ ijọba logun to.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti iṣẹṣe Yorùbá dì apewo ní Cotonou