'Yorùbá yóò gba ìjọba ni 2023 ti wọ́n bá gbé Buhari wọlé ni 2019'

Buhari osinbajo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọṣinbajọ n ṣe ipolongo ojule si ojule ki awọn eniyan le dibo fun Buhari

Ọṣinbajo ṣabẹwo si aafin iku baba yeye ti Ọyọ.

Kini ìròyìn ní Ọṣinbajo sọ?

Lọjọ Abamẹta ni igbakeji aarẹ, ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo kan si Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Olayiwọla Adeyẹmi.

Oṣinbajo parọwa fun iran Yoruba lati dibo gbe Buhari wọle lẹẹkan sii ni 2019 ki iṣejọba le kan wọn pada ni 2023.

O sọrọ yii laafin Ọba Adeyẹmi ko to maa lọ sibi ipade itagbangba gbọngan Atiba nilu Ọyọ.

Oṣinbajo ṣeleri fawọn eniyan Ọyọ pe laipẹ ni wọn yoo wa pin owo okowo 'Trader money' nibẹ lasiko to n gba wọn nimọran lati dibo fun Buhari nitori pe olootọ ni.

O ni ki iran Yoruba ronu lori nkan to m bọ fun wọn ni 2023 lai naani ipenija to n ṣẹlẹ bayii.

O ni irọ ni ahesọ pe APC n gba kaadi idibo lọwọ awọn olokowo ti wọn n fun ni 'trader money'.

Alaafin gbadura pé gbogbo ohun ti iran Yoruba n fẹ ni ọwọ wọn yoo tẹ.

Èrò àwọn ọmọ Naijiria:

Awọn kan gba pe iran Igbo lo kan lati dari Naijiria nitori pe ọwọ wọn ni agbara yẹ ko wa bayii

Bẹẹ ni awọn miran n kilọ fun ijọba yii lati ṣọra nipa ileri ṣiṣe fun iran kankan nitori alaafia

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Awọn mii gba pé ileri yii naa ni wọn ti ṣe fun iran Igbo tẹlẹ ni eyi to fi fẹ jọ irọ́ loju ti wọn pé

Nigba ti awọn kan gbà pé iwa yii ku diẹ káà to nitori pe iran Yoruba ti gbọ́n sii.

Eto idibo 2019 lo ti n kanlẹkun gbọngbọn ni eyi ti awọn oludije ti n tẹra mọ eto ipolongo wọn kaakiri Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Àkọlé fídíò,

Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London