Mr Latin wọlé di ààrẹ ẹgbẹ́ tíátà, TAMPAN

Mr Latin

Oríṣun àwòrán, MR LATIN

Bọlaji Amuṣan, Mr Latin ti sọ pe afojusun oun gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ Theatre And Movies Practitioners Association of Nigeria (TAMPAN) ni lati ri daju pe awọn ọmọ ẹgbẹ n ṣe nkan ti awọn araalu fẹ lati ọdọ wọn.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Mr. Latin sọ pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ TAMPAN ati ANTP pada ni ajọsẹpọ lọjọ iwaju, ṣugbọn kii ṣe nkan to le waye bayi.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2018 ni ẹgbẹ TAMPAN ṣe eto idibo lati yan awọn oloye ẹgbẹ tuntun.

Lopin eto idibo naa to waye niluu Ibadan, Bọlaji Amuṣan ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Mr Latin, lo wọle gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ, nigba ti awọn oṣere bi Ọdunlade Adekọla, Yọmi Fash-Lanso ati Fathia Balogun naa ri ipo di mu.

"Igba ti ijọba wa ba fi idi mulẹ, ta a joko, ti a jọ sọrọ pọ lati mọ boya ki a wa lọtọọtọ tabi ṣepọ ni yoo dara fun wa, nkan ti a ba fẹnuko le lori ni yoo sọ ibi ti ọrọ nlọ."

O tẹsiwaju lati sọ pe ohun to ṣe pataki ni pe ajọṣepọ to dan mọran ti wa laarin ẹgbẹ mejeeji lati igba ti oun ti de ipo.

Ati wi pe ohun to jẹ afojusun oun ni lati ri i daju wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe nkan ti awọn eniyan n fẹ lati ọdọ wọn, gẹgẹ bi olukọ ti awọn eniyan n wo; ninu iwọṣọ, ihuwasi ati isọrọ si wọn.

Ẹgbẹ TAMPAN jẹ ẹgbẹ́ to ya kuro lara, Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners, ANTP l'ọdun 2014.

Àkọlé fídíò,

Gbajúgbajà òsèré tó tún mọ́ ọbẹ̀ sè