Ó pé ọdún 17 tí Bọla Ige kú; àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ rè é

Bọla Ige

Oríṣun àwòrán, Other

Wọn bi James Ajibọla Adekoge Ige l'ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun 1930.

Ilu Zaria ni ipinlẹ Kaduna ni wọn bi si, bi o tilẹ jẹ pe ọmọ ilu Ẹsa-oke, nitosi Ileṣa nipinlẹ Ọṣun ni awọn obi rẹ.

O kawa nileewe girama Ibadan Grammar School laarin ọdun 1943 si 1948, ko to o di pe o lọ si fasiti ilu Ibadan.

Lẹyin naa lo tun lọ si University College, to wa nilu London, nibi to ti gboye imọ ijinlẹ nipa iṣẹ amofin lọdun 1959.

Bọla Ige jẹ kọmisana fun eto ọgbin ni ẹkùn Iwọ Oorun Naijiria laarin ọdun 1967 si 1970 labẹ lasiko iṣejọba Ọgagun Yakubu Gowon.

Àkọlé fídíò,

'IBB da Abiola lẹ́yìn tó búra pẹ̀lú Quran'

Wọn dibo yan an si ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Unity Party of Nigeria, lasiko Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi asiko eto oṣelu ẹlẹẹkeji lọlẹ ni Naijiria.

O wa ni ipo naa di ọdun 1983.

Lasiko eto idibo to waye ni 1983, Ige gbe apoti ibo lẹẹkan si, ṣugbọn Dokita Victor Ọmọlolu Olunlọyọ fi ẹyin rẹ janlẹ.

Lẹyin oṣu mẹta, Olunlọyọ padanu ipo naa nitori iditẹ gbajọba ti Ọgagun Muhammadu Buhari ati Tunde Idiagbọn ṣagbatẹru rẹ.

Lẹyin iditẹgbajọba naa, wọn fi Bọla Ige si ihamọ, wọn si fi ẹsun kan an pe o ko owo ẹgbẹ oṣelu rẹ jẹ. Ṣugbọn, o gba ominira l'ọdun 1985, o si pada si idi iṣẹ amofin ati iwe kikọ.

Àkọlé fídíò,

Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Bọla Ige jẹ ọkan pataki lara awọn to bẹrẹ ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afẹnifẹre.

Nigba ti eto oṣelu awaarawa tun pada l'ọdun 1999, Ige gbiyanju lati dupo aarẹ Naijiria labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD), ṣugbọn wọn ko gba fun.

Aarẹ Olusẹgun Ọbasanjọ to wọle nigba naa yan Bọla Ige gẹgẹ bi Minisita fun Iwakusa ati ipese ina mọna-mọna. O wa ni ipo naa laarin ọdun 1999 si 2000, ko to o di pe o di Minisita fun eto idajọ ati Agbẹjọro Agba fun orilẹede Naijiria.

Amọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2001 ni awọn agbebọn yinbọn pa Ige nile rẹ to wa ni ilu Ibadan.