Àwọn olórin Naijiria pọ̀ tó fakọyọ nilẹ̀ Adulawọ ni 2018

Tiwa ati Wizkid

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Wizkid ati Tiwa da igboro ru p#elu fidio orin yii

Àwọn olórin Naijiria, Ghana àti Cameroon da bira ninu ọdun 2018.

Ọpọlọpọ ninu orin naa ni o bi èso oriṣiiriṣi lawujọ.

Diẹ lara awọn orin to tà dáadáa ti awọn eeyan ilẹ iwọ oorun adulawọ tẹwọgba ni 2018 niwọnyii; nọmba yi ko nii ṣe lori bi wọn ṣe ta tó:

1) Wizkid - Fever

Wizkid onkọrin ọmọ Naijiria kan lo kọ orin 'Fever' ni eyi to gbajugbaja nigba ti wọn gbe awo naa sita.

Fọnran fidio ẹ to jade ni oṣu kẹwa ọdun yii lo tun sọ orin naa di kariaye nigba ti fidio naa ṣafihan Wizkid ati Tiwa Savage.

Bi wọn ṣe jọ jẹyọpọ ninu fidio naa di ọrọ ijiroro lori ẹrọ ayelujara ni eyi ti awọn eeyan mii ṣi n sọrọ le lori di isinyii.

O le ni miliọnu meji eeya to wo fidio naa laarin ọjọ meji ti wọn gbee si ẹrọ ayelujara You tube.

2) Davido - Assurance

Orin yii di orin ti tọmọde tagba n jo si ni kete to jade.

Onkọrin Naijiria, Davido lo fi orin naa fọn rere Chioma to pe ni assurance ololufẹ oun.

Orin yii gba igboro debi pe awọn ololufẹ n beere ẹbun assurance lọwọ ara wọn bi Davido ṣe fun Chioma ololufẹ ẹ.

Oríṣun àwòrán, @Davido

Àkọlé àwòrán,

ọrọ ifẹ lagbara

Àkọlé fídíò,

Davido fi ọkọ̀ Porsche ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí fún Chioma Avril

3) Star Boy to gbé Terri, Spotless, Ceeza Milli ati Wizkid sita - Soco

Awọn Wizkid naa ni wọn gbe orin yii jade. O fi ṣe igi kan ko le da igbo ṣe ni nitori oun ati Terri ati Spotless pẹlu Ceeza Milli ni wọn jọ sọ àwo naa di odindin.

Gbogbo eeyan lo kan sáárá si wọn nigba ti fidio ẹ ṣafihan Chris Brown olorin ilẹ Amẹrika to n jo si orin naa.

4) Burna Boy - Ye

Àrà ọ̀tọ̀ inú orin tó jáde 'Ye' ti Burna gbé sita lọ́dún 2018 ní Nàìjíríà. 'Outside' ni awo na ba jade. Kanye West ọmọ ilẹ́ America gbe awo 'Ye' sita ni eyi to ta pupọ lori itunes.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

5) Falz - This is Nigeria

Ọmọ Naijiria to n kọrin taka sufe Falz lo fi orin to pé akọle rẹ ni 'This is Nigeria' da igboro ru lọdun yii.

Orin naa ṣafihan awọn nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko yii ni eyi to fi gbe awon idojukọ awọn kan ni Naijiria sita.

Orin yii bi ige ati adubi laarin awọn eniyan Naijiria ni eyi ti awọn kan gbà si òdì debi pe ajọ to n mojuto ere idanilaraya ti a n gbe sita ni Naijiria, iyẹn, National Broadcasting Commission fi ofin dee.

Lẹyin eyi ni ajọ Islam ti wọn pe ni Muslim Rights Concern ni ko ko awọn awo rẹ kuro lori igbá. Orin yii ṣi n ta ni ori You tube di isinyi.

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán,

Falz ni ki araye wo Naijiria ti a n gbe loni ninu awo rẹ kan

6) Olamide - Science Student

Orin yii wà lára orin to kọkọ jade ni 2018 ni eyi to da wahala nla silẹ.

Opọlọpọ lo ni orin yii n fọn rere pe ki awọn eeyan maa mu oogun oloro ni eyi to jẹ ki ajọ to n mojuto ere idanilaraya ti a n gbe sita ni Naijiria, iyẹn, National Broadcasting Commission fi ofin dee.

Olamide ni ọtọ ni ọrọ naa ri nitori pe ko sẹni to mọ ede ayan bii ẹni to mu ọpa ẹ dani, pe oun ti oun mu omele dani ni oun mọ nkan ti oun n sọ.

Olamide gbe fidio orin naa sita ni oṣu keji ọdun lẹyin to sọ pe oun n fi orin naa kilọ oogun oloro ni.

7) Davido - Nwa Baby

Orin yii jẹ ọkan lara awọn orin to wọnu ipele nkan ti wọn wá julọ lori google ni Naijiria lọdun 2018. Eyi fihan pe ọpọ ero lo n wa orin yii lori ayelujara.

Won n sọrọ fidio rẹ ti wọn gba pe o dún pupọ ni eyi ti Meji Alabi dari rẹ.

8) Guilty Beatz, Mr Eazi, Patapaa àti Pappy Kojo -Akwaaba

Onkọrin ọmọ ilẹ Ghana, Guilty Beatz lo kọ orin naa. Awọn Banku music lo baa gbe Sample You bo sita ti ọgbẹni Eazi. Akwaaba jẹ orin to mu ẹsẹ ijo tuntun dani ti gbogbo eeyan n jo si ni iwọ oorun ilẹ Afrika.

Orin yii gba ami ẹyẹ meji nibi eto ifami ẹyẹ dani lọla forin to pegede julọ lọdun 2018 nilẹ Adulawọ.

9) Tiwa Savage to ṣe pẹlu Duncan Mighty - Lova lova

Ajọṣepọ yii jẹ ọkan lara awọn to mu eso rere jade julọ lọdun 2018.

Koda Duncan Mighty funra rẹ ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe ajọṣepọ yii lo ta julọ lẹyin Fake Love ti oun ṣe sẹyin. Orin yii de ori igba awọn orin to peleke julọ ni Apple Music fọdun 2018.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

10) Kuami Eugene -Wish me well

Olorin gbajugba ọmọ Ghana, Kuami Eugene lo gbe orin 'wish me well'yii sita lọdun 2018.

O ni orin naa jẹ koriya fawọn eeyan to n la iṣoro kan tabi omiran kọja . O ni oun tun kọọ lati fi ta awọn oluranlọwọ ji ki wọn le ṣe iranlọwọ to ye fawọn to sun mọ wọn.

O tun orin naa sè pọ pẹlu onkọrinayara bi àṣá Naijiria, Ice Prince.

Àkọlé fídíò,

'Wàhálà Boko Haram ló lé mi wá sí Eko tí mo fi di èrò abẹ́ afárá'

11) Daphne - My Lover

Daphne jẹ ọkan lara awọn onkọrin ọmọ Cameroon ti Ọlọrin gab fun lọwọlọwọ ni Cameroon.

Oun lo gba onkọrin obinrin to dara julọ ni aarin gbungbun Afrika lọdun 2018 ninu eto ifami ẹyẹ danilọla fun orin to pegede lọdun 2018.

Àkọlé fídíò,

Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London

12) Mr Real - Legbẹgbẹ

Eyi jẹ ọkan lara awọn orin to sọ ipede ṣakuṣaku di gbajugbaja ni Naijri alọdun 2018.

Oṣu kejila, ọdun 2017 lo jade ṣugbọn ọdun 2018 ni fidio ẹ jade sita.