Ọgọ́rùn ún èèyàn tí pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù Zamfara

Aworan awọn ọdọ to sẹ iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdọ dana sun taya loju ọna

Iroyin to n tẹwa lọwọ lati ipinlẹ Zamfara ni pé awọn olugbe ilu naa ti gbegi dina opopona marosẹ to wọnu ilu lati fẹhonu han lori ipaniyan ati ijinigbe to peleke nibẹ.

Awọn ara ilu Tsafe to jẹ olu ileese ijọba ibilẹ Tsafe ti n fapajanu lori bi awọn ogunlende ati awọn janduku le kuro ni ilu ti wọn ti ṣe yabo ilu tiwọn.

Awọn oluwọde to gbegi dina naa ni o ti ṣu awọn bi awọn alaṣe ko ti ṣe yasi ọrọ aabo titi de ibi to de bayi.

Niṣe ni wọn n sun taya loju ọna lati fidi ẹhonu wọn han lori bi ipaniyan yi ti ṣe peleke.

Alaga ijọba ibilẹ Tsafe, Abubakar Aliyu sọ fun ile iṣẹ BBC pe o le ni eeyan ogoji ti o ti padanu ẹmi wọn ninu abule laarin ọsẹ meji.

Àkọlé àwòrán,

Àarẹ Muhamadu Buhari se àbẹ̀wò sí ágbèègbè náà laipe yii

Lọsẹ to kọja ni awọn janduku wọn yi pa ọpọ eeyan nilu Birnin Magaji tii ṣe ilu Minisita eto aabo Naijiria.

Awọn eleto abọ ti ran ọlọpaa ati ọmọ ogun lati pẹtu saawọ lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Àkọlé fídíò,

'Wàhálà Boko Haram ló lé mi wá sí Eko tí mo fi di èrò abẹ́ afárá'