Ipenija awakọ̀ àti arinrinajo lásìkò ọdún

Ipenija awakọ̀ àti arinrinajo lásìkò ọdún

Ka ma rin lọjọ ti ebi ba n pa ọna ni adura ti ọpọ eniyan saba maa n gba, paapa julọ lasiko ọdun.

Jakejado orileede Naijiria, ni papakọ ofurufu tabi ni awọn ibudokọ to wa kaakiri,awọn eniyan n wa ọkọ tabi nnkan irinsẹ miran ti yoo gbe wọn lọ si ile ọdun.

Ikọ BBC Yoruba sabẹwo si awọn ibudokọ kan to wa ni ilu Eko lati wadii ipenija ti awakọ maa n ṣe alabape nigba ti wọn ba n rinrinajo.

Ọrọ naa ko yọ awọn arinrinajo silẹ, ti awọn naa ṣi salaye ohun ti oju wọn maa n ri lasiko ọdun.

Bi awọn kan ti ṣe n sọrọ nipa alekun owo ọkọ,sunkẹrẹ fakẹrẹ loju ọna marosẹ, l'awọn miran n foya nipa awọn ọlọsa to ma n da awọn eeyan lọna lasiko yi.

Pataki julọ,awọn ti ikọ BBC Yoruba ba sọrọ sọ wi pe pẹlẹ kutu ṣe pataki lati le dele layọ ati alaafia.