'EFCC mo dé' àti àwọn àṣà míì táwọn olóṣèlú fi dagbo rú ní 2018

Aworan Gomina Ayodele Fayose

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Àkọlé àwòrán,

Niṣe ni Ayo Fayose daku gbaranganda nibi ipolongo idibo Gomina Ekiti

Awọn oloṣelu Naijiria dagbo oṣelu ru daadaa lọdun 2018

Bi wọn ti ṣe sọ awọn nnkan to ṣe awọn eeyan ni kayefi, ni ọrọ wọn miran mu inu bi ara ilu ti awọn mii si n dẹrin pa wọn.

Awọn eeyan a ma fi oju apọnlẹ wo oloṣelu gẹgẹ bi ẹni ọwọ, ati olori to mọ iwe daadaa. Nitori eyi,gbogbo nnkan ti wọn ba ṣe a ma mu iriwisi orisirisi wa.

Ẹ jẹ ki a ran ara wa leti diẹ ninu awọn asiko manigbagbe ni 2018 ati ọrọ ti awọn ọmọ Naijiria ko le gbagbe ati ju bẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti Aarẹ Buhari yoo ko iyan awọn ara ilu rẹ kere lẹyin odi

#LazyNigerianYouths - Muhammadu Buhari / oṣu kẹrin, 2018

Yoruba bọ,wọn ni bi a ba ta ara ile ẹni lọpọ, a ko le ri ra l'ọwọn.

Rẹgi lọrọ yi ṣe losu kẹrin ọdun 2018 nigba ti awọn ọdọ Naijiria tutọ soke, foju gba lori bi wọn ti ṣe ni Ààrẹ Buhari sọ wípé àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kò fẹ ǹkan ṣe.

Kia ni wọn ti bẹrẹ 'hash-tag' lori ayelujara lati fẹhonu han. Esi ti awọn eeyan fun un pada wi pe awọn kii ṣe ọlẹ lori Twitter ko rẹrin rara.

Àkọlé fídíò,

Ajimọbi: Pé Ayefẹlẹ jẹ́ àkàndá kò fún láṣẹ láti rú òfin

Eeyan ko gbọdọ sọ pe t'ori oun jẹ alaabọ ara ko máa rufin-Abiola Ajumọbi

Gbolohun yi jẹ ọkan ti awọn ọmọ kaarọ ojiire ko ni gbagbe lọdun 2018.

O jẹyọ nigba ti Gomina Ajimobi ti ipinlẹ Oyo n fesi si ẹsun wi pe o paṣẹ ki wọn wo ile iṣẹ rẹdio gbajugbaja akọrin, Yinka Ayefẹlẹ niluu Ibadan.

Ọpọ lo bẹnu atẹ lu igbesẹ yi sugbọn lẹyin o rẹyin Ajimọbi ati Ayefẹlẹ pari ija ti Gomina Ajimọbi si tun ṣe iranwọ lati tun ile iṣẹ naa kọ.

Àkọlé fídíò,

Ayefẹlẹ - Ara ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kọ òtítọ́ ní wọ́n ṣe fẹ́ wó iléèṣẹ́ rédíò mi

'Am in pains' - Ayodele Fayose / Oṣu keje, 2018

Awọn oloṣelu naa a ma sunkun. Bi a ko ba mọ telẹ, Gomina ipinlẹ Ekiti ana Ayodele Fayose lo jẹ ki a mọ.

Oríṣun àwòrán, @Ogundamisi

Àkọlé àwòrán,

Fayose sọ wi pe awọn ọlọpaa lo ṣe ohun leṣe

Nibi ipolongo ẹgbẹ oselu PDP lasiko ti idibo gomina waye ni ipinlẹ Ekiti, ni Fayose ti fara han lori ẹrọ amohunmaworan ti o si figbe ta wi pe awọn ọlọpaa na oun.

Ki ilẹ ọjọ naa to ṣu ,Fayose sun gbalaja sori ibusun alaisan ti gbogbo aye si ri bi wọn ti ṣe gbe digbadigba wọnu ọkọ alaisan.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ

Transmission, Transmission - Ibrahim Idris / Oṣu karun un, 2018

Yoruba ni, aṣiwi ko to aṣisọ.

Lootọ, Ọga agba ọlọpaa Naijiria, Ibrahim Idris kii ṣe oloṣelu ṣugbọn lọdun 2018, awọn kan gba wi pe iṣesi rẹ kan ko jẹ ki a fẹ mọ iyatọ laarin oun ati awọn oloṣelu.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Àkọlé àwòrán,

Ibrahim Idris, ọga agba ọlọpa Naijiria

Idi rẹ ti o fi da bi wi pe awọn ọmọ Naijiria ko gbagbe rẹ ni bi o ti ṣe n kalolo nibi to ti n sọrọ lode kan nibi ti o ti fẹ ṣe ifilọlẹ kan.

Gbolohun 'Transmission Transmission' rẹ ti o n tẹnumọ pa ọpọ eeyan lẹrin ti o si mu ki awọn kan ṣe kayefi iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Ipenija ojú kò di Ademola lọ́wọ́ láti kẹkọọ gboye

Àkọlé fídíò,

Wòlíì Àrólé sọ àsọtẹ́lẹ̀ s'áyé BBC ní London

Wakati mọkanla ni mo lo lori igi - Dino Melaye / Oṣu keje, 2018

Saaju ki o to kuro ninu ẹgbẹ APC lọ si PDP, ilumọọka oloṣelu to jẹ Sẹnatọ to n ṣoju ipinlẹ Kogi, Dino Melaye ti halẹmọ awọn ọlọpaa wi pe oun yoo pa ara oun si wọn lọrun .

Àkọlé àwòrán,

Dino Melaye lórí ìbùsùn

Ninu ọdun 2018 kan naa lo pada tun sọ pe oun sa si ori igi fun wakati mọkanla nigba ti o ni awọn kan fẹ gbẹmi oun.

Melaye ni ori lo ko oun yọ lọwọ awọn apaniyan ọhun ati wi pe bi ki baa ṣe wi pe oun sapamọ sori igi, ọta ko ba ti ri oun gbeṣe.

Awọn ọlọpaa ni irọ pọnbele ni Melaye pa lori iṣẹlẹ naa to lo waye loju ọna marosẹ Abuja si Lọkọja.

Àkọlé fídíò,

'Wàhálà Boko Haram ló lé mi wá sí Eko tí mo fi di èrò abẹ́ afárá'

EFCC mo de! - Ayodele Fayose / Oṣu kẹwaa, 2018

A o ka ẹsẹ eto yi nilẹ pẹlu Gomina Ekiti ana, Ayodele Fayose lẹẹkansi.

Ajọ to n gbogun ti jẹgudujẹra lorileede Naijiria, EFCC kede pe ni kete to ba pari saa ijọba rẹ lawọn yoo wọ lọ si ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Lere Ọlayinka: Ayo Fayose sí wà ní gbaga àwọn EFCC

Fayose ko tilẹ jẹ ki wọn wa ki o to yọju si ile iṣẹ ajọ naa ni Abuja ti o si wọ aṣọ dudu ti wọn kọ akori "EFCC I am here" si.

Ọrọ yi dagboro ru gan an ti awọn kan si bẹrẹ si ni ta aṣọ ti wọn kọ ọrọ yi silara ni witiwiti.

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Àkọlé àwòrán,

Gomina Wike ati Fani-Kayode kọwọrin pẹlu Fayose lọ si ile iṣẹ ajọ Efcc