Sophie Oluwole: Màmá Onímọ̀ Òye kọjá lọ lẹ́ni ọdún 83

Sophie Oluwole

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Àkọlé àwòrán,

Sophie Oluwole tó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ àsà àti ìse Yoruba àti ilẹ́ Afirika lápaapọ̀ ti papòdà ní ẹni ọdún 83

Awọn ọmọ kaarọ oojiire ti n kẹdun Ọjọgbọn Sophie Oluwole to dagbere fun aye ni ẹni ọdun mẹtalelọgọrin.

Sophie Oluwole ni wọn bi ni agbeegbe Igbara-Oke ni ipinlẹ Ondo ni ọdun 1936, ti o si kawe gboye lati fasiti Ile-Ifẹ ni bi ogoji odun seyin.

Akẹẹkọ gboye onimọ oye, Sophie Oluwole to tun jẹ Ọjọgbọn ninu imọ asa, ise Yoruba ati ti ilẹ Afirika lapapọ dagbere fun aye ni ọsan Ọjọ Isinmi, lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Gbajugbaja oniroyin, Funmi Iyanda sọ nipa igbe aye oloogbe naa to bu iyi kun imọ ilẹ adunlawo nipa oselu, idagbasoke ile Afirika ati ọrọ aje naa.

Taiwo Obe naa fikun wipe Sophie Oluwole ti awọn eniyan ma n pe ni "mamalawo" lo jẹ obinrin akọkọ to kawe gboye ọmọwe ni orilẹede Naijiria.

Ọjọgbọn Oluwole naa to kọ ọpọlọpọ akẹẹkọ ni fasiti ilu Eko, ni ọpọ eniyan mo wi pe o sa ipa rẹ fun igbelarugẹ awọn obinrin, imọ ijinlẹ Yoruba ati ti ilẹ adulawo lapaapọ.